Movement Charter/Drafting Committee/Archived/yo
Ìgbìmọ̀ Kíkọ ti Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀ |
---|
Ètò |
Ìdìbò àti Ìyàn |
Iṣẹ́ |
Movement Charter content |
Get involved |
Frequently Asked Questions For email enquiries: movementcharterwikimediaorg |
Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀ yí ò fi ipa àti ojúṣè oníkálukú àti oníṣẹ́ hàn lórí àjọṣepọ̀ Wikimedia. Yí ò jẹ́ ìlànà fún àjùmọ̀ ṣ'iṣẹ́ pọ̀ lọ sí Ìdojúkọ Strategy.
Ìgbìmọ̀ fún Kíkọ ti Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀ ni yí ò kọ ìwé-àdéhùn yìí. Ọ̀rọ̀-ìmúlò wọn yí ò tẹ̀lé Ọ̀rọ̀-Ìmọ̀ràn Strategy Àjọṣepọ̀ ti "Equity in Decision-Making". Iṣẹ́ ìgbìmọ̀ náà tayọ kíkọ ìwé-àdéhùn nìkan. Wọn yí ò tún ṣe àwọn ìwádìí àti ìkànsí pẹ̀lú àwọn ará àjọṣepọ̀, àwọn amòye, àti àwọn àjọ. Ìwé-Àdéhùn yí ò wà fún ètò ìfọwọ́sí tó gbòòrò kárí àjọṣepọ̀ yìí.
Ẹgbẹ́ yìí yí ò ní àwọn ará 15. À nretí wípé ẹgbẹ́ yìí yíò ní ọríṣiríṣi ẹ̀yà, èdè, orílẹ̀-èdè, àti ìrírí káàkiri àjọṣepọ̀ yìí. Lára rẹ̀ ni ìkópa nínú àwọn iṣẹ́-àkànṣe, àwọn ẹ̀ka Wikimedia àti Wikimedia Foundation. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ síi wo: Drafting Committee matrices.
Ìmọ̀ ède gẹ̀ẹ́sì kò ṣe pàtàkì láti jẹ́ ọmọ ìgbìmọ̀ yìí. Àtìlẹ́yìn fún ìtúmọ̀ wà, tí ìwúlò bá wà fún. Àwọn ará yí ò máa gba owó láti ran ìkópa wọn lọ́wọ́. Iye eléyìí ni US$100 lẹ́ẹ̀kán ní oṣù méjì.
Members
Tentative list of members (based on the official announcement, 2021-11-01):
Àwọn Ìmọ̀ṣe fún Ipò
À nretí kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà:
- Hùwà ní ànfààní àpaapọ̀ àjọṣepọ̀ yìí.
- Tèlé Ìdojúkọ Strategy àti Àwọn ìmọ̀ràn Strategy Àjọṣepọ̀.
- Tèlé Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí.
- Léè ya wákàtí bíi máàrún sọ́ tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún ọdún kan. Ìgbà yìí ó ma yípadà bíi iṣẹ́ bá ṣe pọ̀ sí.
- Léè darapọ̀ mọ́ àwọn ìpàdé orí ayélujára.
- Léè ṣiṣẹ́ ní àjọ tó dá lórí ìpohùnpọ̀ àti àìfohunpamọ́.
- Ṣetán láti yàn àti gbe àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ titun wọlé tí ọmọ ìgbìmọ̀ kankan bá fi ipọ̀ rẹẹ̀ sílẹ̀.
- Láti má wà ní abẹ́ ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ lórí iṣẹ́-àkànṣe Wikimedia kankan tàbí lát'ọ̀dọ̀ Wikimedia Foundation.
- Ṣe àfihàn ara rẹ̀ sí Wikimedia Foundation. Àwọn ènìyàn fún ipò yìí gbọdọ̀ fi ohun ìdánimọ̀ wọn hàn ní dandan. [1]
Irú Ọmọ Ìgbìmọ̀ Tánwá
À nwá àwọn ènìyàn tó:
- Mọ bí a tí njùmọ̀ kọ ìwé. (àfihàn ìrírí yí ó wúlò)
- Ṣetán láti wá ìkoríta àdéhùn.
- Dojúkọ inclusion àti diversity.
- Ní ẹ̀bùn láti rí àwọn àlàfo tí ó nílò dídí.
- Ní ìmọ̀ ètò ìkànsí fún àwọn ará Wikimedia.
- Ní ìrírí Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ káàkíri ọríṣiríṣi àṣà.
- Ní ìrírí ètò ìjọba tàbí ìdarí àwọn àjọ àti àjọṣepọ̀ àìṣe t'èrè.
- Ní ìrírí ìdúnadúrà láàrin àwọn ẹgbẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Àkíyèsi: A ò retí wípé kí ènìyàn kan ní gbogbo ohun wọ̀nyí. À nretí irú ìgbìmọ̀ tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yí ò ṣe àṣekún ara wọ́n. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, wo Drafting Committee matrices.
Ètò
- Ìgbìmọ̀ náà yí ò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ènìyàn 15.
- Tí a bá rí iye ènìyàn tó ju 20 lọ, àdàlú ètò ìdìbò pẹ̀lú yíyàn yí ò wáyé.
- Tí abá rí iye ènìyàn tí kò tó 20, ètò yíyàn nìkan ni yí ò wáyé láì sí ìdìbò.
E lè rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ètò níbí.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Ọmọ Ìgbìmọ̀
If you wish to read the statements of the Drafting Committee candidates, click here.
Nominations for the Movement Charter Drafting Committee were closed on 14 September. Elections were held between October 12, 10:00 UTC to October 24, 2021 (AoE).
The results of the elections and selection processes were published on 1 November 2021.
Àwọn Àkíyèsí
- ↑ Wọ́n lè lo ọ̀kan lára: ìwé ìwakọ̀, ìwe ìrìnnà tàbí àwọn ohun ìdánimọ̀ ìjọba míràn tí ó fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ orúkọ àti ọjọ́ orí hàn. Wọ́n lè fi eléyìí hàn Wikimedia Foundation lórí secure-infowikimedia.org.
Àkíyèsi: Fún àwọn iṣẹ́ àṣetẹ́lẹ̀ lórí ìgbìmọ̀ fún kíkọ, wo ojú-ewé yìí.