Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí/Àwọ̀n ìjíròrò 2021/Àwọ̀n ará Yorùbá

From Meta, a Wikimedia project coordination wiki
Jump to navigation Jump to search
This page is a translated version of the page Universal Code of Conduct/2021 consultations/Enforcement/Yoruba community and the translation is 100% complete.
Other languages:
<translate> Universal Code of Conduct</translate>

A dá Wikipedia èdè Yorùbá sílẹ̀ ní oṣù kẹ́rin, ọdún 2004. Ní àkókò oṣù kẹ́ta, ọdún 2021, Àwọn onísẹ́ mẹ́rin lé l’áàdọ́ta (54) pẹ̀lú alákòso mẹ́ta (3) ní ó nṣisẹ́ lọ́wọ́ ní iṣẹ́ Wikimedia yìí. Láti ìgbà tí a ti dá èdè Wikipedia yìí sílẹ̀, àwọn àròkọ 33,000 lati ṣ'ẹ̀dá s’órí Wikipedia yìí, pẹ̀lú àwọn àtúnṣe tí ó lé ní 530,000[1] Wikipedia èdè Yorùbá nṣe ìgbàsílẹ̀ àwọn onkà bí mílíọ̀nù mẹ́ta ní osoòṣù.[2]

Ní ọjọ́ kíní, oṣù kẹ́jọ, ọdún 2019, Wikimedia Foundation ṣe ìdánimọ̀ fún egbẹ́ àjọṣepọ̀ Wikimedia ti Yorùbá (Yoruba Wikimedians User Group). Ẹgbẹ́ àjọṣepọ̀ yìí n ṣẹ̀tò àwọn iṣẹ́ oríṣiríṣìi ní Nàìjírìà, bí ìwọ́de àti ìpolongo fún Wikimedia, ìdánilẹ́kọ̀ọ́, àti àwọn àpèjọ. Ẹgbẹ́ ajosepo Wikimedia ti Yorùbá ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ bíi ogún (20).

Àwọn ìlànà fún Ìwà wíwù lóri Wikipedia Yorùbá

Lọ́wọ́ lọ́wọ́, kò sí ìlànà pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ tí o nṣe ìtọ́sọ́nà fún ìwà wíwù tàbí àwọn ojúṣe lóri Wikipedia èdè Yorùbá. Bó tilẹ̀ jẹ́ wípé, a lèrí àwọn ojú-ewé ìlànà kọ̀kan lóri isẹ́ Wikimedia yìí, àwọn ojú-ewé yìí ṣábà máá njẹ́ àdàkọ tàrà láti orí àwọn ojú-ewé ìlànà àtijọ́ Wikipedia èdè gẹ̀ẹ́sì. Pẹ̀lúpẹ̀lú, ọ̀pọ̀ lára àwọn ìlànà wọ̀nyí ni wọ́n sì wà ní èdè gẹ̀ẹ́sì tí a ti dà wọ́n kọ, láì sí ìtumọ̀ sí èdè Yorùbá.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìjíròrò ojúkojú tí a ṣe, àwọn oníṣẹ́ kọ̀kàn ṣ’àfihàn wípé, irú ipọ̀ báyì léè fa wàhálà nítorí pé, àwọn ìgbésẹ̀ awọn alákòso ma nsábà dá lórí ìdájọ́ tí ara wọn (tí ó ma nsábà dá lórí ohun tí wọ́n ti kọ́ làt’òri Wikipedia ti gẹ̀ẹ́sì) dípò àwọn ìlànà tí ati fìdí wọ́n múlẹ̀ nípasẹ̀ ìjíròrò àti ìpohùnpọ̀ àwọn oníṣẹ́ Wikipedia Yorùbá.

Pẹ̀lúpẹ̀lú, nítorí àìsí àwọn ìlànà ìbílẹ̀, àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n darapọ̀ mọ́n àjọṣepọ̀ Wikimedia nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́-àkànse tí ó tóbi (bí Wikipedia gẹ̀ẹ́sì) máa nsábà ṣe àgbéwọlé àwọn òfin àti ìlànà iṣẹ́-àkànse tí wọ́n ti nbọ̀ sí nu Wikipedia Yorùbá.

Ètò Ìjíròrò

Breakdown of Participation Platforms

Ìkànsí àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia ti Yorùbá bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kíní; ósì wá ṣ’íparí ní ọjọ́ kẹ́ta, oṣù kẹ́ta, ọdún 2021; ìjíròrò wọ̀nyí wáyé fún òsẹ̀ méje àti ọjọ́ díẹ̀. Ní àkókò yìí, a ké sí àwọn ará àti ọmọ ẹgbẹ́ nípasẹ̀ orísirísi ọ̀nà àti pẹpẹ tí àwọn ará ti n lò tẹ́lẹ̀ fún àwọn ìjíròrò àti ìkéde wọn. Làra wọn ni:

  1. Abẹ́ Igi: A bẹ̀rẹ̀ ìkòrí ìjíròrò lóri Abẹ́ Igi Wikipedia Yorùbá ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kíní, ọdún 2021. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ìjíròrò pàtàkì kìí sábà wáyé lóri àbẹ́-igi, ojú-ewé yìí sì ti maá n sábà jẹ́ pẹpẹ fún oríṣìríṣì àwọn ìkéde. Nítorínáà, ìjíròrò kankan kò ti ojú-ewé yìí wáyé, sùgbọ́n ó ṣì wúlò fún fífi tó àwọn oníṣẹ́ Wikipedia yìí létí.
  2. Social media: Àwọn ìjíròrò pàtàkì pẹ̀lú àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikmedia ti Yorùbá, pàtàkì jùlọ Yoruba Wikimedians User Group wáyé nípasè àwọn ohun èlò social media. Ó fẹ́rẹ̀ẹ̀ jẹ́ wípé gbogbo àwọn ìfitónilétí àti ìkédèe sí àwọn ará àjọṣepọ̀ yìí gba àwọn ohun èlò social media ẹgbẹ́ náà kọjá. Ní àkókò ètò ìkànsí àti ìjíròrò UCOC yìí, ìkédè mẹ́tàlá ni a ṣe sí àwọn pẹpẹ social media láti darí àwọn ìjíròrò tí óún lọ lọ́wọ́ ní oríṣiríṣi ìgbà.
  3. Ìpàdé orí ayélujára: Aṣe ètò ìpàdé kan lórí ayélujára ní àkókó ìkànsí àti ìjíròrò yìí, láti pèsè ọ̀nà fún àwọn ará àjọṣepọ̀ láti fi àwọn èrò inú wọn hàn lórí bí a ṣe lè fi òfin de Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí tí ó wà nlẹ̀. Ìpàdé yìí tún jẹ́ ọ̀nà tí a gbà láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ lóri UCoC fún àwọn ará àjọṣepọ̀ wikimedia Yorùbá tí wọn kò tí gbọ́ ohunkóhun lórí UCoC tẹ́lẹ̀.
  4. Àwọn Ìjíròrò Ojúkojú: A ké sí àwọn olórí ẹgbẹ́ Wikimedia Yorùbá àti àwọn oníṣẹ́ tí ó já fáfá jù fún àwọn èrò inú wọn lórí àkórí fífi òfin de UCoC. A ṣe eléyìí láti pèsè àbò fún àwọn ará tí ó bá fẹ́ sọ ohun tí wọn kò fẹ́ kí àwọn ará àjọṣepọ̀ tó kù fi ṣẹ̀ wọ́n tàbí tí ó lè fa ìyọlẹ́nu ọjọ́ iwájú.
  5. Iwe-iwadii: A tún pín àwọn ìwé ìwádìí láti pèsè ọ̀nà fún àwọn ará àjọṣepọ̀ tí wọn kò bá fẹ́ fojú hàn fún àwọn ọ̀nà tókù tí a pèsè, tàbí àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àbò fún ìdánimọ̀ ara wọn. A pín ìwé-ìwádìí wọ̀nyí lóri ayélujára, nípasẹ̀ ojú-ewé Wikipedia Yorùbá, láti àárín osù kéjì ọdún 2021, títí dé ìparí ìkànsí àti ìjíròrò UCoC yìí.

Ní àkótán, àwọn ènìyàn 49 ni ó fèsì sí àwọn ìpè wa, tí wọ́n sì dásí ọ̀rọ̀ yìí nípasẹ̀ oríṣiríṣi àwọn pẹpẹ tí a ti làkalẹ̀ ní àkókò ìkànsí àti ìjíròrò yìí. Arí èsì 19 nípasẹ̀ ìwé-ìwádìí, asì rí èsì láti ọ̀dọ̀ àwọn arábìnrin 18 láàpapọ̀.

Èsì Àwọn Ará Àjọṣepọ̀

Gender Demographics of Consultation

Láàpapọ̀, arí àtilẹyìn tí ó lágbára fún fífi òfin de Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Wikimedia Yorùbá. Ìgbàsílẹ̀ ìtakò kan ni arí ní gbogbo àkókò ìjíròrò, ósì dá lóri bí a ò ṣe kánsí àwọn ará èdè Yorùbá ní ipele àkọ́kọ́ ìkànsí yìí ní ọdún 2020.

A ṣe àkójọ àwọn èsì yìí nípasẹ̀ ìwé-ìwádìí tí a pín:

  • 47.4% àwọn olùkópa ni kò mọ̀ rárá, tàbí mọ̀ dájú àwọn ìlànà fún ìwà wíwù lórí Wikipedia ti Yorùbá.
  • 15.78% àwọn olùkópa ni wọ́n sọ wípé àwọn ti rí ìyọlẹ́nu láti ọ̀dọ̀ oníṣẹ́ ní ipò alákòso Wikipedia, bẹ́ẹ̀ni 5.26% àwọn olùkópa ni sọ wípé àwọn òtí rí ìyọlẹ́nu ní ojú ayé, nítorí àwọn iṣẹ́ Wikimedia wọn.
  • Kòsí ìkankan làra àwọn olùkópa yìí tí ó ṣe ìjábọ̀ àwọn ìyọlẹ́nu tí ó kàn wọ́n sí wíkì.

Èsì Lóri Ẹgbẹ́ Agbófìnró

Ní àsìkò àwọn orísiríṣi ìjíròrò ará àjọṣepọ̀, àwọn ìpohùnpọ̀ wáyé lóri ṣíṣe ìṣẹ̀dá ìgbìmọ̀ pàtàkì tí yí ó ma ṣe ìwádìí àti ìdájọ́ lóri àwọn ẹ̀sùn ìyọlẹ́nu. Iyàn wáyé lóri pé, ìgbìmọ̀ yìí (àti àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀) gbọdọ̀ ní ìjọba tí àwọn àlákòso Wikipedia kò le dásí, láti ríi dájú wípé àwọn ìwádìí àti ìdájọ́ lóri ẹ̀sùn tí ó bá kàn àwọn àlakòso àti oníṣẹ́ tí kò nípò yí ò jẹ́ òdodo láìsí àbàwọ́n.

Àwọn èrò wáyé tí ó tako ìdásí tàbí ìdaríi Wikimedia Foundation lórí ìgbìmọ̀ agbófìnró, tàbí fífi òṣìṣẹ́ Wikimedia foundation sí orí ìgbìmọ̀ náà. Ìdí fún èrò yìí ni wípé, àwọn ìyọlẹ́nu orí Wikipedia máà nṣábà dá lórí àwọn àròkọ ojú-ewé Wikipedia; nítorí náà, kò tọ̀nà fún Wikimedia Foundation láti dásí ẹgbẹ́ agbófìnró yìí, nígbàtí a ti kéde ní oríṣiríṣi ọ̀nà wípé Wikimedia Foundation kìí darí àwọn àròkọ tó wà lórí Wikipedia tàbí àwọn òfin tí ó de àròkọ wọ̀nyíí.

Pẹ̀lúpẹ̀lú, àwọn àtìlẹyìn tún wà fún ṣíṣẹ̀dá ìgbìmọ̀ yìí láti wùwà gẹ́gẹ́ bíi ìgbìmọ̀ àfilọ̀, tí yóò gbà ẹ̀sùn wọlé lẹ́yìn tí olùfisùn bá ti lo àwọn ọ̀nà Wikipedia rẹẹ̀ láti yọrí ọ̀rọ̀ ìyọlẹ́nu, sùgbọ́n kò sí ìyanjú. Síbẹ̀síbẹ̀, ìgbìmọ̀ yìí sì tún lè jẹ́ ibi àkọ́kọ́ tí olùfisùn yí ò wá tí kò bá sí ìlànà tàbí ìgbìmọ̀ pàtàkì fún ìwádìí ìṣòro rẹ̀ lórí Wikipedia ti iyolenu náà ti ṣẹlẹ̀.

Èsì sí ọ̀rọ̀ yìí yàtọ̀ díẹ̀ lórí ìwe-ìwádìí, níbi tí 57.89% àwọn olùdáhùn ti rò wípé ìgbìmọ̀ ìgbófìnró UCoC yẹ kí ó ní àkójọpọ̀ ọ̀kan tàbí jùbẹ́ẹ̀lọ lára àwọn oníṣẹ́ tí ó já fáfá, àwọn alákòso, àti àwọn òṣìṣẹ́ Wikimedia Foundation. Síbẹ̀síbẹ̀, 36.84% àwọn olùdáhùn sì rò wípé ìgbìmọ̀ ìgbófìnró gbodọ̀ jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn oníṣẹ́ tí kò nípò kankan, bẹ́ẹ̀ni 5.26% àwọn olùdáhùn ní èrò wípé, àwọn alákòso orí Wikipedia ni kí ó ṣe ìwádìí àti ìdájọ́ ìyọlẹ́nu.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn èsì tí a rí nípasè ìwé-ìwádìí wa, 57.89% àwọn olùdáhùn ni ó rò wípé ó yẹ kí a san owó tàbí irú ẹ̀bùn míìràn fún àwọn olùfarajìn tí ó bá kópa nínú ìgbìmọ̀ ìgbófìnró UCoC, bẹ́ẹ̀ni 42.11% t’ókù wà láàrin, láìṣe àtìlẹ́yìn tàbí àtakò. Àì sí àtakò kankan sí ìbéèrè yí tọ́ka sí ìpohùnpọ̀ fún àtilẹ̀yìn irú ètò báyìí.

Èsì Lórí Ipa-ọ̀nà Ìgbófìnró àti Àwọn Ìkànnì fún Àtúnyẹ̀wò

Ní ìgbà àwọn ìjíròrò ará àjọṣepọ̀ yìí, ìpohùnpọ̀ tí ó lágbára wáyé lórí dídá àbò tí ó dájú bo ìdánimọ̀ àwọn olùfisùn àti àwọn olùfaragba ìyọlẹ́nu, nínú àkókò ìwádìí àti ìgbà ìdájọ́. Nínú Ìwé-ìwádìí wa, 94.74% àwọn olùdáhùn ni ó ṣe àtìlẹyìn fún ètò ìfisùn tí yíò dá àbò bo olùfisùn àti olùfaragba ìyọlẹ́nu, bẹ́ẹ̀ni àwọn 84.21% ni ó tún rò wípé ìwádìí tí ó ṣe àbò fún ìdánimọ̀ ṣe pàtàkì ju ìwádìí igbangba lọ. Àwọn ọ̀rọ̀-àfikún lórí àbò ìdánimọ̀ sì tún wáyé sí nínú àwọn àsọyé tí a rí nínú àwọn èsì ìwé-ìwádìí wa.

Lára àwọn àpẹrẹ tí àwọn olùdásí dá lábà ni - ṣíṣètò e-mail tí àwọn ènìyàn lè gbà fi ẹ̀sùn kàn ní ìkọ̀kọ̀. Ìwádìí irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀ yí ò wá wáyé pẹ̀lú àbò tí ó dájú fún àwọn ènìyàn tí ó bá fi ẹ̀sùn kàn. Àbá míìràn tún ni fífi bọ́tìnì sí ojú-ewé wikipedia tí àwọn onísẹ́ lè tẹ̀ láti bá ènìyàn sọ̀rọ̀ (lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, pẹ̀lú àbò ìdánimọ̀).

Lákòkò àwọn ìjíròrò, ìpohùnpọ̀ tí ótún wáyé ni wìpé, àwọn ìwádìí ẹ̀sún tí ó bá ti kọjá agbára ìgbìmọ̀ ìgbófìnró yí ò jálọsí ẹ̀ka Trust and Safety ti Wikimedia Foundation. Ní ọ̀rọ̀ míìràn, È̩ka Trust and Safety ti Wikimedia Foundation lè jẹ́ ibi ìparí fún ìwádì tí kò bá lójùtú tí ìgbìmọ̀ ìgbófìnró UCoC lè fi dájọ́. Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì díẹ̀ wà látọ̀dọ̀ ìwé-ìwádì, níbi tí 57.89% àwọn olùdáhùn rò wípé ẹ̀ka Trust and Safety ti Wikimedia Foundation ni kí ó jẹ́ ipele tí ó kàn tí ọ̀rọ̀ kòbá ní ojútù fún ìgbìmọ̀ UCoC àkọ́kọ́, nígbàtí 42.11% tókù lérò wípé óyẹ kí a ṣ’ẹ̀dá ìgbìmọ̀ míìràn tí ótún ní ohun àmúlò gíga láti dásí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Nítorínà, nínú gbogbo àwọn ìjíròrò yìí, arí wípé ìdábà ètò oní’pele mẹ́ta ni àwọn ènìyàn faramọ́. Àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbìmọ̀ oríi iṣẹ́ àkànṣe tí ọ̀rọ̀ ti ṣelẹ̀, ìkejì jẹ́ Ìgbìmọ̀ ìgbófìnró UCoC gboogbò, ìkẹ́ta yí ò sì jẹ́ ẹ̀ka Trust and Safety ti Wikimedia Foundation.

Èsì Lóri Ìwọ̀n Àsìkò fún Ìwádìí Ìgbófìnró

Nínú ìwé-ìwádì, 63.16% àwọn olùdáhùn ló fún wa ní àkókò gbòógì tí wọ́n gbérò wípé ètò ìwádì gbọdọ̀ lò, nígbàtí àwọn olùdáhùn tó kù kán sọ́ àwọn àfikún lóri bóṣe yẹ kí a yan àsìkò tí ó yẹ fún ìwádì.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn èsì ìwé-ìwádìí, 83.33% àwọn olùdáhùn tí wọ́n fún wa ní àkókò gbòógì fí mọ̀ ṣọ̀kan wípè gbogbo ìwádìí àti ìdájọ́ kò yẹ kó ju oṣù kan lọ́, pẹ̀lú ìgbà tí ó kéré jùlọ nínú ìdáhùn jẹ́ òsè kan. 8.33% àwọn olùdáhùn sọ wípé ètò yìí yẹ kí ó wáyé láàrín ọjọ́ mẹ́ta sí máàrún, nígbàtí àwọn 8.33% tókù sọ wípé ètò yìí lè gba osú mẹ́fà sí méjìlá.

Láàrín àwọn 36.84% olùdáhùn tókù tí kò fún wa ní àkókò gbòógì, 62.50% rò wípé àkókò tí ìwádìí àti ìdájọ́ yẹ kí ó gbà kó dá lóri bí ọ̀rọ̀ náà ṣe yii tó àti bí ó ṣe ní ìṣòro sí, pẹ̀lú ìrú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwádìí tí ó ní lò. Àwọn 37.5% tókù rò wípé ìwádìí lè gba bí óti l'ẹ́tọ̀, níwọ̀n ìgbà tí ìdájọ́ bá ti jẹ́ òdodo láìsí àbàwọ́n.

Àwọn Ìdáhùn Ìpín-kékeré

Ní àsìkò ìjíròrò yìí, àwọn àbá wáyé lóri bí a ṣe lè ríi dájú wípé ẹnikẹ́ni kó fi ipá mú ìgbìmọ̀ agbófìnró UCoC, àti wípé àwọn ìwádìí pẹ̀lú ìdájọ́ pé ojú-ìwọ̀n láì sí ojú-ìsájú. Lára wọn ni: Ìdálẹ́kùn àwọn ará ìgbìmọ́ láti má ṣe dásí àwọn ẹ̀sùn tí ó bá kan iṣẹ́ àkànṣe tí ará náà ti wá, àti ṣíṣe ìgbékalẹ̀ ìlànà tí kò ní f’àyè gba àwọn alákòso wikipedia ìsinyìí tàbí titẹ́lẹ̀ nínú ìgbìmọ́ náà.

Ìtọ́ka sì tún wáyé wípé onírúurú ènìyàn ni ógbọdọ̀ wà lórí ìgbìmọ̀ agbófìnró UCoC tí a fẹ́ dásílẹ̀ yìí; nítorínà, ìgbìmọ̀ yìí kò gbọdọ̀ ṣe ti àwọn ẹgbẹ́ kan, akọ tàbí abo, tàbí ẹ̀yà kan, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ, láti dẹ́kùn ojú-ìṣájú nínú àwọn ìwádìí àti ìdájọ́ tí ìgbìmọ̀ náà bá nṣe.

Èsì Lóri Ríran Àwọn Olùfaragba Ìyọlẹ́nu Lọ́wọ́

Àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia Yorùbá lérò wípé dídá ẹgbẹ́ àtìlẹyìn sílẹ̀ tí àwọn olùfaragba ìyọlẹ́nu lè darapọ̀ mọ́n jẹ́ ìmọ̀ràn tí ó dára. Wọ́n rò wípé irú ètò báyìí jẹ́ ọ̀nà tí ó dára láti lè ran ìlera ọkàn àwọn ará àjọṣepọ̀ yìí, àti ìlera àjọṣepọ̀ yìí pẹ̀lú, ní ìṣọ̀kan.

Sùgbọ́n, àwọn olùdáhùn síbẹ̀ fi ìkìlọ̀ hàn wípé, ìmójúto àti ìdarí tí ó péyé gbodọ̀ wà fún irú ẹgbẹ́ àtilẹyìn báyìí láti ṣe ìdènà fún ìwà ìbàjẹ́ àti láti ríi dájú wípé ẹgbẹ́ yìí ṣe àwọn nkan tí ati dásílẹ̀ fun.

Àwọn Ìtàn/Ìmọ̀ràn/Àkíyèsi tí ó ṣe Gbòògíì

Ní ìgbà ìjíròrò pẹ̀lú àwọn ará àjọṣepọ̀, oníṣẹ́ kan sọ ìrírí rẹ̀ ní odún díẹ̀ sẹ́yìn, lóri ohun tí wọ́n pẹ̀ ní ìdojú-ìjà àwọn ẹgbẹ́ alákòso Wikipedia èdè gẹ̀ẹ́sì tó t’ẹnu ìfojúsíni lára wá. Gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ ná ṣe ròyìn, àwọn ẹgbẹ́ alákòso yìí gbèrò lé oníṣẹ́ yìí lórí, wọ́n sì ṣe ìpaláyà àti ìyọlẹ́nu ní gbogbo ọ̀nà, lára rẹ̀ ni títú àṣírí iṣẹ́ tí wọ́n ṣe àtí ibi tí wọ́nti ṣiṣẹ́.

Oríṣiríṣi ìwúrí fún ìgbèrò sí oníṣẹ́ yìí wáyé ní ojú-ewé ayélujára tí kò wà lára àjọṣepọ̀ Wikimedia, ṣùgbọ́n ipa rẹ̀ njẹ́ gidi gidi lórí ojú-ewé àkíyèsi fún àwọn alákòso ti Wikipedia èdè gẹ̀ẹ́sì. Oníṣẹ́ yìí pàtàkì jùlọ dárúkọ búlọ́ọ̀gì kan tí wọ́n pè ní “Wikipediocracy”, gẹ́gẹ́ bí ojú-ewé ayélujára tí àwọn oníṣẹ́ orí Wikipedia ti sọ̀rọ rẹ̀ láì da ní gbangba, tí kòsì sí ohun tí òfin Wikipedia àti Wikimedia lè ṣeṣí. Àwọn oníṣẹ́ látòrí búlọ́ọ̀gì ná wá n lọsí orí ojú-ewé àkíyèsi fún àwọn alákòso ti Wikipedia èdè gẹ̀ẹ́sì láti koná sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀ títí tí àwọn alákòso fi f’òpin bá ìwàláyè rẹ̀ẹ̀ ní Wikipedia èdè gẹ̀ẹ́sì.

Oníṣẹ́ yìí sọ ìrírí yìí ní ìbátan pẹ̀lú ìbéèrè lóri bí aselè ṣe ìwádìí àti ìdájọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìyọlẹ́nu tí ó nṣẹlẹ̀ ní àwọn ibi tí ipa àti òfin Wikimedia kò dé, sùgbọ́n tí ìyọlẹ́nu náà ti ara ìdarapọ̀ àti ṣíṣe àwọn iṣẹ́ àjọṣepọ̀ Wikimedia wá.

Ìparí

Breakdown of Consultation Demography

Ètò Ìkánsí àti ìjíròrò pẹ̀lú àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia Yorùbá lọ ní ìrọwọ́ rọ’sẹ̀, ósì já sí àṣeyọrí. Àwọn èsì tí arí tó pé gbóríyìn, ní pàtàkì jùlọ, tí a bá ro iye àwọn oníṣẹ́ tí onsiṣẹ́ nínú Wikipedia yìí. Pẹ̀lúpẹ̀lú, tí wọ́n tún íjẹ́ àwọn oníṣẹ́ tó wá láti ẹ̀ka àgbáyé tí àwọn ohun èlò ayélujára sì gbówólórí nítorí dátà ìlópin, ó jẹ́ ohun tí ó ṣ’àpẹẹrẹ rere wípé àwọn ará yìí sì tún yàn láti jọ̀wọ́ àwọn ohun èlò wọ̀nyí fún ìdarapọ̀ mọ́n ètò ìjíròrò àti ìwádìí UCoC yìí. Adúpẹ́ gidigidi fún àdúrósinsin yín yìí!

Nínú àwọn ìjíròrò tí a ṣe, kò sí àtakò kan gbòógì sí Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí tàbí ìgbófìnró rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ará àjọṣepọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn míìràn nífẹ̀sí títún àlàkalẹ̀ náà ṣe sí (nítorí wípé a ò ké sí àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia Yorùbá ní ìgbà ipele àkọ́kọ́ ti kíkọ àlàkalẹ̀ ná). Ṣùgbọ́n bí ọ̀pọ̀ tilẹ̀ rọ̀ báyìí, wọ́n síbẹ̀ fara mọ́ ìlànà yìí bí ótirí lọ́wọ́, wọ́n sì rò wípé yí ò ní ipa tí ó dára lórí àjọṣepọ̀ wọn, níwọ̀n ìgbà tí ìgbófìnró ná báti péye.

Ní àkótán, àwọn ará àjọṣepọ̀ yìí fara mọ́n ètò yíyan ìgbìmọ̀ ìbílẹ̀ láàrín àwọn olùfarajìn tí wọ́n ti ní ìrírí tí ó nípọn láti ṣe ìgbófìnró UCoC, ṣùgbọ́n ìpohunpọ̀ tún wáyé wípé ẹ̀ká Trust and Safety ti Wikimedia Foundation ni kí ó yanjú àwọn ẹ̀sùn tí ó bá kọjá agbára ìgbìmọ̀ yìí. Àwọn olùdáhùn sì retí wípé ìwádì gbọdọ̀ wáyé kíákíá, kí èsì si àwọn ẹ̀sùn má sì ju osù kan lọ.

Pẹ̀lúpẹ̀lú, àtìlẹ́yìn tí ó lágbára wà fún bíbo ìdánimọ̀ àwọn olùfaragbà àti olùfinsùn ìyọlẹ́nu, wọ́n sì tún ṣe àtìlẹyìn fún ìwádì ìkọ̀kọ̀. Àwọn olùdáhùn tún ṣe àtìlẹ́yìn fún sísan ọwọ́ tàbí irú ẹ̀bùn míìràn fún gbogbo àwọn olùfarajìn tí ó bá nṣiṣẹ́ lórí ìgbìmọ̀ yìí, kòsì sí àtakò kankan sí ṣíṣ’ètò ẹgbẹ́ àtìlẹyìn fún àwọn olùfaragbà ìyọlẹ́nu níwọ̀n ìgbà tí ìmójútó àti ìdarí ìgbìmọ̀ yìí báti péye.

Àwọn Ìtọ́kasí