Jump to content

User:Olaide07

From Meta, a Wikimedia project coordination wiki

Yorùbá

Orúkọ mi ni Jimoh Ridwan Olaide. Mo jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gboyè onípò kìn-ín-ní nínú ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá (B. A Yoruba) ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀dá Èdè àti Àwọn Èdè ilẹ̀ Áfíríkà, ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti yunifásítì Ìbàdàn, Ìbàdàn. Mo jẹ́ ẹni kan tí ó nífẹ̀ẹ́ sí èdè Yorùbá púpọ̀, èyí ló sì mú mi tẹ̀síwájú nínú kíkọ́ èdè Yorùbá ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga, mo parí pẹ̀lú first class honours ní èdè Yorùbá. Mo jẹ́ oníṣòwò kátàkárà, mò ń ta àwọn nǹkan ẹ̀yà ara fóònù. Bẹ́ẹ̀ sì ni mo jẹ́ òǹgbufọ̀, mo lè ṣe òǹgbufọ̀ èdè Yorùbá sí èdè Gẹ̀ẹ́sì bẹ́ẹ̀ sì ni láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Yorùbá. Bákan náà ni mo tún jẹ́ olùkọ́ èdè Yorùbá, mo ń kọ àwọn ènìyàn tí ó nímọ̀ díẹ̀ tí wọ́n sì fẹ́ mọ̀ sí i tàbí tí kò ní ìmọ̀ nípa èdè Yorùbá rárá tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí i láti kọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí èdè àkọ́kúntẹni. Mo ti ṣe àwọn àfikún díẹ̀ lórí ìmọ̀ ìwé ọ̀fẹ́ (wikipedia) èyí tí ó lé ní ọ̀ọ́dúnrún. Lára àwọn ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìfiga-gbága tí mo ti kópa ni :bí a ṣe lè lo ìmọ̀ ìwé ọ̀fẹ́, oúnjẹ ilẹ̀ Áfíríkà, àwọn ajìjàgbara tó gbajúmọ̀ ní ilẹ̀ Áfíríkà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

English

My name is Jimoh Ridwan Olaide. I graduated from the department of Linguistics and African Languages (B. A Yoruba), Faculty of Arts, University of Ibadan, Ibadan. I love Yoruba language a lot, this makes me studied Yoruba language in higher institutions, I graduated with first class honors in Yoruba language. I am entrepreneur, I deal with phone accessories. I am also a translator, I translate from Yoruba language to English language as well as from English language to Yoruba language. I am also a Yoruba teacher, I teach people who have little knowledge and want to know more or didn't have any prior knowledge about Yoruba language and will like to learn it as a second language. I have made some contributions on Wikipedia which is above 300 edits. Part of training and competition I have took part in are : how to use Wikipedia, African cuisine, popular activists in Africa and so on.