Jump to content

WikiProject UNESCO/Wiki Loves Earth Biosphere Reserves page translation

From Meta, a Wikimedia project coordination wiki
This page is a translated version of the page WikiProject UNESCO/Wiki Loves Earth Biosphere Reserves page translation and the translation is 100% complete.

Please add your translations of the Wiki Loves Earth Biosphere Reserves 2016 competition page so they can be added to the website, the website currently has translations for:

 • English
 • French
 • Spanish
 • Russian
 • Ukrainian

Content

 • Wiki Loves Earth 2016 has not started yet. Wiki Loves Earth will start in June. You may still share your images, but they will not be eligible for the competition.
 • Welcome to the Wiki Loves Earth contest! This is the upload wizard for photos of protected natural objects and areas.
 • Wiki Loves Earth 2016 is closed. You may still share your images, but they will not be part of the competition.

Se apínlò fọ́tò tí o yà nípa Àwọn Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí UNESCO Fipamọ́ ní Wikipedia fun ẹ̀kọ́ kíkọ́ àti ìwúrí gbogbo ayé.

Wiki Loves Earth tí ní ìbáṣepọ pẹ̀lú UNESCO lati ṣẹ̀dá Wiki Nifẹ́ Àwọn Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́, èyí tí ó jẹ́ idije fótò yíyà lati ṣẹ̀dá àwòrán ọ̀fẹ́ ti Àwọn Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ káàkiri gbogbo ayé ní Wikimedia Commons, ojú òpó mídía fún Wikipedia

Wọ́n máa ṣàfihàn àwòrán mẹwá tí ó bá gbégbá orókè ní ojú òpó búlọ́ọ̀gì Ènìyàn UNESCO àti ojú òpó wẹ́ẹ̀bù ti Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí, àwọn oníṣẹ́ ìtàkùsọ́rọ̀ UNESCO máa pín, wọ́n sì máa dije nínú international Wiki Loves Earth competition.

Wiki Loves Earth

Wiki Loves Earth jẹ́ ìdíje fọ́tò yíyà gbogboògbò nípa àwọn ibi àdáyébá tí ó wà lábẹ́ ààbò, ní ọdún 2015 àwòrán tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọrún ni àwọn tí ó kópa lati orílẹ̀ èdè mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n tẹ̀ wọlé. Wiki Loves Earth tún ń ṣẹlẹ̀ fún gbogbo agbèègbè tí ó wà lábẹ́ ìdáàbòbò ní àwọn orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kan, wọlé síbí lati mọ̀ si nípa bí o ṣe lè kópa.

Àwọn Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́

Àwọn Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ jẹ́ àwọn agbèègbè orí ilẹ̀ àti omi tàbí méjèèjì, tí gbogbo àgbáyé mọ̀ níkawọ́ àwọn ètò àjọ UNESCO fun Ènìyàn àti Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí (MAB). Ìkọ̀ọ̀kan Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ máa ṣe ìgbéga àwọn ọ̀nà àbáyọ lati ṣagbátẹrù ìtọ́ju ìpínsíyẹ́lẹyẹ̀lẹ Ohun Ẹlẹmí fún lílò. Loní, Àwọn Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ jẹ́ 669 ní orílẹ̀ èdè 120 tí ó jẹ́ ti àsopọ̀ àgbáyé ti Àwọn Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́.

Kópa

Wikipedia jẹ́ ìkan lára ohun àmúlò jùlọ fún ẹ̀kọ́ lagbáyé, tí àwọn ènìyàn tí ó ju bílíọ́nú márùndínlógún ma ń wò lóṣoosù. Wikipedia máa ń jẹ́ kí a ṣiṣẹ́ papọ̀ lati kọ́ àwọn ènìyàn lẹkó nípa àgbáyé àti bí a ṣe lè gbé ìgbé àlááfíà. O lè ya fọ́tò ohunkóhun tí ó nííṣe pẹ̀lú Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ bíi ẹ̀yà, àlà ilẹ̀, ìpínsíyẹ́lẹyẹ̀lẹ Ohun Ẹlẹmí, ìyípadà ojú ọjọ́, ìdàgbà sókè ìmúlò àti oríṣiríṣi àṣà.

O tún lè ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ lati kópa:

 • Pínlò iṣẹ́ Facebook yìí
 • Tún iṣẹ́ kúkurú yìí ran ní twitter ẹ
 • Kànsí àwọn alaṣẹ Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ ní orílẹ̀ èdè rẹ kí o sì sọ fún wọn nípa ìdíje yìí
 • ̣Ṣe ìfilọ̀ ìdíje yìí pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ oní fọ́tò, ilé ẹ̀kọ́ gíga àti àwọn ẹgbẹ́ tí ó bá mọ̀ pé ó lè fẹ́ kópa. Ìdíje yìí máa jé àànfàní ńlá fún àwọn àwùjọ àti àwọn àjèjì sí Awọn Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ lati ya àwọn fọ́tò àwọn ibi wọ̀nyí, àti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa wọn síi.

Oriṣiriṣi ọ̀nà ni àwọn Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ míràn tókù lè gbà bá Wikimedia ṣiṣẹ́, fún àlàyé síwájú sì́i jọ̀wọ́ tẹ ibí. Ìròyìn nípa ìdíje yìí wà ní ojú òpó wẹ́ẹ̀bù UNESCO níbí àti ní ojú òpó wẹ́ẹ̀bù Wikimedia Foundation níbí.

Bí o ṣelè wọlé

Tẹ Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ nínú àwòrán ayé tí ó wà nís̀lẹ̀:

 1. Tẹ̀ lórí Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ lati lọsí ojú ewé UNESCO fún Àwọn Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ fún ìwadi síi nípa ojú òpó àtí àwọn ìjápọ sí ojú òpó wẹ́ẹ̀bù Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ àti àwòrán ayé níbi ti ó báwà.
 2. Tẹ Wọlé sí ìdíje kí ó lè gbé ẹ lọsí Wikimedia Commons lati fi ẹ̀dà fáìlì rẹ fún Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ yẹn ṣọwọ́.
 3. Ṣẹ̀dá orúkọ oníṣẹ́ ní Wikimedia Commons tàbí kí o fi oníṣẹ́ rẹ tẹ́lẹ̀ wọlé, Jọ̀wọ́ máṣe lo orúkọ ilé iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ.
 4. Fi àdírẹ́sì ímeèlì rẹ sí oníṣẹ́ rẹ ní Wikimedia Commons ní abala ààyò rẹ.
 5. Ìṣẹ̀dà fáìlì lè gba àádọ́ta àwòrán lẹ́ẹ̀kan náà. Tí ó bá wú ọ́ lati gbé àwòrán wọlé síi jọ̀wọ̀ tẹ àjápọ̀ lórí àwòrán ayé lẹ́ẹ̀kan síi. Kò sí iye àwòrán tí o kò lè gbéwọlé.

Àkíyèsí: ọ̀pọ̀lọpọ̀ Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí ló gba àyè púpọ̀ àwọn agbèègbè, fún ìdí èyí ojú ibi tí wọ́n wà nínú àwòrán ayé kólè ṣojú ibi wọ̀nyí, àlàyé síwájú síi wà nípasẹ̀ títẹ̀lé á̀jápọ̀ sí ' Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́.

Òfin

Gbogbo àwòran gbọ́dọ̀ jẹ́:

 • Èyí tí o yà; Gbogbo àwòrán gbọ́dọ̀ jẹ́ ojúlówó àwòran tí ẹni tí ó yàá fi ṣọwọ. Àwọn fọ́tò tí ẹlòmíran yàtọ̀ sí ẹni tí ó yàá fi ṣọwọ́ máa dìkọ̀sílẹ̀.
 • Fi àwòràn ṣọwọ́ lakókò tí ìdíje ń lọ lọ́wọ́ (Ọjọ́ karún Oṣù karún - Ọgbọ̀n ọjọ́ Oṣù karún Ọdún 2016); O tún lè fi fọ́tò tí o ti yà tẹ́lẹ́ sílè. Ohun tí ó ṣe kókó ní kí o fi fọ́tò yí ṣọwọ́ lakókò tí ìdíje ń lọ lọ́wọ́ .
 • Wà lábẹ́ àṣẹ lílò ọ̀fẹ́
 • Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ tí wọn dámọ̀: o lé rí àkójọpọ̀ àwọn ibi wọ̀nyí nínú àwòrán ayé nísàlẹ̀ tàbí lórí ojú òpó wẹ́ẹ̀bù Ènìyàn àti Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí.
 • Àwọn àwòrán lè jẹ́ ìmúsí èyíkeyí, síbẹ̀síbẹ̀ ókéré jù, àwọn àwòrán gbọ́dọ̀ tó bíi Megapixels méjì (1600x1200) kí ó tó lè wọ ìdíje gbogboògbò.
 • Fi fáìlì ṣọwọ́ pẹ̀lú lílò àwòrán ayé nísàlẹ̀; Àwọn àwòran ti ó bá gbé wọlé láìtẹ̀lé ìlànà Wikimedia Commons upload wizard kó ní wọlé fún ìdíje.
 • Ọ̀fẹ́ ni o lè kópa nínú ìdíje yìí, tí kò sì sí iye àwòrán tí o kò lè gbé wọlé.
 • Àwọn àwòrán mẹwá tí ó bá gbégbá orókè máa wọlé fún ìdíje gbogboògbò, àwọn òfin fún ìdíje gbogboògbò wà [wikilovesearth.org/rules/ níbí]
 • O lè gbé àwọn àwòrán sí Wikimedia Commons nígbàkúùgbà ṣùgbọ́n kó lè wọlé fún ìdíje lẹ́yìn Oṣù kẹfá Ọdún 2016.

Àwọn iṣẹ́ ṣíṣe míràn

Ní àfikún sí Wiki Loves Earth Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ UNESCO tí ṣètò ìṣàpèjuwe Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́ lábẹ́ àṣẹ Creative Commons tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ àwùjọ Wikimedia lati ṣe ìyípadà wọn sí àwọn àyọkà Wikipedia fún gbogbo Apá Ilé Ayé tí ó jẹ́ Ibùgbé Ohun Ẹlẹmí tí a fi Pamọ́. Ṣe ìwadí síwájú síi níbí

Ti o ba ni nnkan se pelu ápá ibi táwọn èèyàn lè gbé lórí ilẹ̀ ayé ti o si nife si ìsọfúnni lori awon ìgbòkègbodò miran, jowo ṣíra tẹ ibi yii

Ìtúnlò àwọn àwòrán

Gbogbo àwọn àwòrán tí ó wà ní Wikimedia Commons àti àwọn tí a ṣẹ̀dá bí ara ìdíje yìí wà fún lílò lọfẹ́, fún àlàyé síwájú síi bí a ṣe lè tún àwọn àwòrán lò tẹ ibi.

Fún ìbéèrè àti àti àwọn àlàyé síwájú síi jọ̀wọ́ kànsí J.Cummings@unesco.org

 • Ẹranko tí Yúróòpù ti ó ń jẹ oyin (Merops apiaster) ní Ichkeul National Park and Biosphere Reserve, Tunisia. Photo by Elgollimoh, freely licensed under CC BY-SA 3.0.
 • Carpathian Biosphere Reserve, Zakarpattia Oblast, Ukraine. Photo by Vian and retouched by Iifar, freely licensed under CC BY-SA 4.0.
 • Cormorants at dusk on the pond of Vaccarès, part of Delta du Rhone Biosphere Reserve, France. Photo by Ddeveze, freely licensed under CC BY-SA 3.0.