Oníṣẹ́ Emna Mizouni, ẹni tí ó gba oríyìn Wikipedia fún ti ọdún 2019.

From Meta, a Wikimedia project coordination wiki
Jump to navigation Jump to search

Oníṣẹ́ Emna Mizouni, ẹni tí ó gba oríyìn Wikipedia fún ti ọdún 2019.

Emna WikiIndaba.jpg

Wọ́n kéde Oníṣẹ́ Emna Mizouni tí ó jẹ́ olùpolongo àti olùfọnrere Iwe-Ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ (Wikipedia) tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Tunisia gẹ́gẹ́ bí Oníṣẹ́ Wikipedia fún ti ọdún 2019. Wọ́n fun ní Amin-ẹ̀yẹ yí látàrí akitiyan àti àṣeyọrí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣíwájú rere nínú àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìtànkálẹ̀ Wikipedia ìyẹn (global Wikimedia movement), pàápàá jùlọ láàrín àqọn elédè Lárúbáwá (Arab) áti àwùjọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ (Africa), àti fún isẹ́ ìwúrí rẹ̀ láti mú ìdàgbàsókè bá eyan àti àṣà ilẹ̀ abínibí rẹ̀.

Emna ni ó jẹ́ olùgbé ìlú Tunis tí ó jẹ́ Olú ilu fún Tunisia fún ìgbà pípẹ́. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe gbe kalẹ̀, Tunis ni ó wà ní àrin méjì ìwọ̀ Oòrùn àti Ilé Oòrùn Òkun Mediterranean ní èyí tó ṣokùnfà kí ó jẹ́ olú ìlú fún ilẹ̀ Ọba Carthaginia, èyí tí ìjọba re fìdí kalẹ̀ sí erékùṣù orílẹ̀-èdè Spain sí Gúsù ilẹ̀ Adúláwọ̀ àti Corsica. Ilẹ̀ Ọba parun ní nkan bí 164 BCE sẹ́yìn, àmọ́ wọ́n tún gbe dide ní abẹ́ àkóso Umayyad Caliphate, ní èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú nlá ńlá sì wà níbẹ̀ dòní

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀rùndún ọdún, Emna ṣe anẹ̀wò sí orígun mẹ́rin ìlú rẹ̀, ó sì jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fun wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn àgbọ́ minu ni ó fara-sin fún àwọn ènìyàn. Láti ṣe èyí, Emna àti àwọn ènìyàn kan kórajọ pọ̀ láti da ẹgbẹ́ kan tí wọ́n porúkọ rẹ̀ ní Carthagina, ẹgbẹ́ tí kìí ṣe ti ìjọba ní ọdún 2013 . Gẹ́gẹ́ bí Emna ṣe sọ, óní: "Pẹ̀lú ìgbésẹ̀ yí, a gbèrò láti ṣàfikún, dáábòbò, àti láti gbe àṣà, ìtàn àjogúnbá orílẹ̀-èdè wa fún ìwúlò ọjọ́ iwájú"

Pẹ̀lú ìlépa nla báyí, Wikimedia ni ibùwọ̀ fún àjọ Carthagina. Emna bẹ̀rẹ̀ sí ní kópa nínú ìṣeẹ́ Wikimedia, pàá pàá jùlọ ìdíje Wiki Loves Monuments ti ọdún 2013, ìdíje tí ó wà fún ìṣàfihàn àwọn àwòrán ohun ọ̀ṣọ̀ tí Elédùmarè fi jíìnkí wa. Ó ṣàfikún tirẹ̀, ó sì rọ̀ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ kí àwọn náà ó ṣe tiwọn náà. mí

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún Emna tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ Ìgbòkègbodò Wikimedia lágbàáyé, ó sì gbìyànjú láti ri wípé Ile ri àti ìlapa èrò Wikimedia ń wà sí ìmúṣẹ nípa akitiyan rẹ̀ láti mú kí àwọn ènìyàn ja ànfàní Iwe inọ̀ ọ̀fẹ́ káàkàkiri àgbáyé. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hẹ́ wípé isẹ́ ìbáni-sọ̀rọ̀ àti ìlànà itajà ni iṣẹ́ tí ó yàn láàyò, síbẹ̀, ó si ń kópa tó lààmì-laaka nínú isẹ́ tí ó Wikipedia tí àwọn ènìyàn Kò mọ̀ nípa rẹ̀.

Ó Se pe: " Mo nígbàgbọ́ nínú ìlànà ijẹ́ Olórí tó fara sin (invincible leadership)", ẹ̀wẹ̀, Ó tún Se pe: " Gbogbo ènìyàn agba ni ó ní ẹ̀bùn láti mú iṣẹ́ tí ó lágbára tí àjọ Wikimedia gbe dání. Emi náà Kò yàtọ̀ sí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn tókù bí mo ṣe ń da sí iṣẹ́ náà pẹ̀lú ọpọlọ tí Ọlọ́hun fún mi".

Lara àwọn iṣẹ́ Wikimedia tí ó ń ṣe ni láti ṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́, ìpéjọpọ̀ lóríṣiríṣi nípa Wikipedia fún àwọn ènìyàn pàá pàá jùlọ Àpéjọpọ̀ WikiArabia irúfẹ́ alákọ̀ọ́kọ́ irú rẹ̀ tí wọ́n ó ṣe fún àwọn oníṣẹ́ Wikipedia Lárúbáwá tí ó wáyé ní ọdún 2015. Irúfẹ́ àpéjọpọ̀ yí tún wáyé ní ọdún 2017 ní ìlú Káírò (Cairo). Òun náà lo tún ṣe adarí fún àpéjọpọ̀ Wikimania ti ọdún 2018, tí ó sì jẹ́ wípé òun ni ó ṣagbátẹrù bí ètò ọlọjọ́ márùún náà ṣe kẹ́sẹjárí. Ó tún darapọ̀ mọ́ ìgbìmọ̀ alábàáṣe (Affiliations Commitee) Wikimedia ní ọdún 2016, ó sì di ìgbà-kejì Alága ìgbìmọ̀ náà ní ọdún 2018. Ìgbìmọ̀ yí ni ó jẹ́ ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni méjìlá tí ó ń kópa nínú ètò ìdìbò yani sí ipo àṣẹ nínú ìgbìmọ̀ náà, nigba tí àwọn tókù tí kìí kópa jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdámọ̀ràn, àti alákòóso àwọn Irúfẹ́ ìgbìmọ̀ báyí fún àjọ Wikimedia nípa ṣíṣàgbékalẹ̀ àwọn ètò ọlọ́kan ò jọ̀kan ìlànà fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí Wikimedia.

Emna tún tẹ̀ síwájú si láti ṣagbátẹrù ìgbékalẹ̀ àkójọ àkọsílẹ̀ Orí-ọ̀rọ̀, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn isẹ́ mìíràn tí ó jẹ́ tara rẹ̀ láti mú kí àjọ Wikimedia ó túnọ̀ gbòòrò síwájú si ní ilẹ̀ Tunisia. Òun náà ṣí ni Alága àgba fún àjọ Carthagina tí ó sì ti mú ìlépa èrò ajo Carthagina síwájú si nípa dídá ètò ẹ̀kọ́ Digital Citizenship kalẹ̀, tí ó sì jẹ́ àjọ tí kìí gbowó lọ́wọ́ àwọn ènìyàn, tí ó sì ń kéde inọ̀ ẹ̀kọ́ ayélujára àti àbò fún àwọn tí Kò lẹ́nu lọ́rọ̀ láwùjọ.

Ó ní: " N ó ma gbìyànjú láti ma ṣàwárí ọ̀tun nípa àṣà àti ìtàn níbi tí àyè bá ti gbáà mí", Ó tún ní " pàá pàá jùlọ àwọn ibi tí ìwòye imọ̀ wa Kò tii de".

Ed Erhart, Olótùú Àgba fún ètò ìbánisọ̀rọ̀
Àjọ Wikimedia

Amin-ẹ̀yẹ ìdánilọ́lá Wikimedia ọlọ́dọọdún ri Àjọ Wikimedia ma ń ṣe ni ó ma ń wáyé látọwọ́ olùdásílẹ̀ àjọ náà, ìyẹn Ọ̀gbẹ́ni Jimmy Wales ní ìpàgọ́ Wikimania, ìpàgọ́ tí ó ma ń ṣàjọyọ̀ nípa iṣẹ́ Wikipedia àti àwọn iṣẹ́ tó fara pẹ, àti àwọn Oníṣẹ́ Olùfínúfíndọ̀ Wikipedia tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ aláìníye. Lọ́dún yí, òun àti Ọ̀gbẹ́ni Farhad Fatkullin tí ó jẹ́ ẹni tí ó gba ami ẹ̀yẹ Wikimedia ti ọdún 2018, láti kéde olúborí Amin ẹ̀yẹ ti ọdún yii Emna Mizouni.
Ìkéde yí wà láti ọwọ́ Àjọ Wikimedia ní Orí ìkànì ayélujára Àjọ Wikimedia ní ọjọ́ Kẹrìndínlógún osu Kẹ́jọ, ọdún 2019 (16-08-2019), ní bi tí ó ti wà lábẹ́ CC BY-SA 3.0.