Jump to content

Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ Wikimedia Foundation/Àkópọ̀

From Meta, a Wikimedia project coordination wiki
This page is a translated version of the page Wikimedia Foundation Board of Trustees/Overview and the translation is 94% complete.
Outdated translations are marked like this.

Wikimedia Foundation
Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́


Njẹ́ o mọ̀ wípé nígbàtí ò nka ojú-ewé Wikipedia tí o fẹ́ràn jùlọ, àwọ́n ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ni ó nṣiṣẹ́ láti rí dájú wípé ìmọ̀ ọ̀fẹ́ yìí wà ní ọ̀fẹ́?

Àwọn ará àjọṣepọ̀ ni ó wà káàkiri àgbáyé tí ó jẹ́ kí àwọn isẹ́-àkànṣe nlá bíi Wikipedia, Wikidata, Wikisource, etc. wà láàyè.

Wikimedia Foundation ni ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ náà. Àjọ yìí ni ó nṣe ìtọ́jú fún àwọn ohun èlò ayélujára, àwọn ìpèníjà òfin ìjọba, àti àwọn ìṣòro.

Wikimedia Foundation ní Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ tó bojútó àwọn iṣẹ́ àjọ yìí. À nyan àwọn onígbọ̀wọ́ yìí lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará àjọṣepọ̀ ní apákan, àti lát'ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ fún ra rẹ̀ ní apákejì.

Àga 16 ni ó wà nínú Ìgbìmọ̀ yìí:
Àga mẹ́jọ̀o (8) fún àwọn ará àti ẹ̀ka Wikimedia,
Àga méjèe (7) fún àwọn tí ìgbìmọ̀ yán, àti
Àga kàn (1) fún olùdásílẹ̀.

Onígbọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan yí ò lo odún mẹ́tàa lórí àga rẹ̀.


Yíyàn fún àwọn àga lát'ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ má nwáyé nípa ètò ìwárii kárí-ayé. Wọn yí ò darapọ̀ mọ́ ìgbìmọ̀ nígbàtí ìgbìmọ̀ àwọn onígbọ̀wọ́ àti ẹni-ayàn náà bá ti gbà wípé iṣẹ́ náà yẹ fún wọn.

Àwọn ará Wikipedia yí ò ní ànfààní láti dìbò fún onígbọ̀wọ́ lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará àjọṣepọ̀. Eléyì pèsè ànfààní láti lè mú àlékún bá ṣíṣojú, ìkójọ pọ̀ ìmọ̀ ọlọ́kan-ò-jọ̀kan àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ náà ní ìrísí ẹgbẹ́.


Àwọn onígbọ̀wọ́ yí ò jọ̀wọ́ wákàtí 150 fún iṣẹ́ wọn lọ́dọọdún. Wọn yí ò ṣiṣẹ́ nínú ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ orí ìgbìmọ̀ náà. Lára àwọn ẹgbẹ́ yìí ni: Board Governance, Audit, Human Resources, Product, Special Projects, àti Community Affairs.
A ó ṣe àtẹ̀jáde àwọn àkọsílẹ̀ ìpàdé ìgbìmọ̀ yìí ní gbangba ní ojú-ewé ìpàdé Foundation Wiki tàbí lórí àwọn ojú-ewé ìgbìmọ̀ náà.
Mọ̀ si nípa Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ àti bíí o ṣe lè kópa nínú ìdìbò ìgbìmọ̀ yìí lórí: https://w.wiki/yY9.