Wikimedia Foundation elections/2021/2021-09-01/2021 Voting Closes/yo
Adúpẹ́ fún ìkópa rẹ nínú Ètò Ìdìbò Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ Wikimedia Foundation 2021! Ìdìbò parí ní 31 August ní 23:59. A ó kéde àwọn dátà, pẹ̀lú àwọn olùdíje mẹ́rin t'óní ìbò jùlọ, nígbàtí àwọn Ìgbìmọ̀ Elétò Ìdìbò bá ti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àpótí ìbò. A ó ṣe ìkéde Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ titun níwájú, nígbàtí Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ báti fọwọ́sí àwọn olùdíje tí a ti yàn.
Àwọn ará Àjọṣepọ̀ 6,946 lát'órí iṣẹ́-àkànṣe wiki 216 lóti dìbò. Eléyìí jásí iye olùkópa kárí-ayé 10.2%, ó fi 1.1 ogorun ojuami lé ní iye olùkópa ìdìbò ti tẹ́lẹ̀. Ní 2017, àwọn ènìyàn 5,167 lát'órí wiki 202 ni ó dìbò. À ngbèrò láti ṣe àgbéjáde ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àtúpalẹ̀ láìpẹ́, lẹ́yìn tí a bá ti kéde èsì ìdìbò. Ní ẹnu ìgbà yìí, o lè wo àwọn dáta tí a gbàkalẹ̀ láàrín ìdìbò.
Ìfojúsìn wa nínú ìdìbò yìí ni láti kànsì onírúurú ènìyàn. A túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ lórín ètò ìdìbò sí èdè 61. Ètò ìpolongo yìí lọ dáradára. Àwọn ará àjọṣepọ̀ 70 ló ní àwọn oníṣẹ́ tó ní àṣe láti dìbò nínú ìdìbò yìí fún ìgbà àkọ́kọ́. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ, ètò ìdìbò Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ ti ọdún tó nbọ̀ yí ò dára jùlọ.