Universal Code of Conduct/Newsletter/3/Global message/yo

From Meta, a Wikimedia project coordination wiki
This page is a translated version of the page Universal Code of Conduct/Newsletter/3/Global message and the translation is 100% complete.

Ìròyìn Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí - Abala Ìkẹ́tàa

Ìròyìn Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí
Abala ìkẹ́tàa, Oṣù kẹ́jọ̀ọ 2021Ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn


A kí yin káàbọ̀ sí abala ìkẹ́tàa Ìròyìn Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí! Ìwé ìròyìn yìí yio ran àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tó nṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí ìlànà yìí, a ó sì tún pín àwọn ìròyìn, ìwádìí, àti àwọn àpèjọ tó jọmọ́ UCoC tó nbọ̀ lọ́nà.

Tí ẹ kò bá tí ṣ'eléyìí tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ rántí láti fi orúkọ sílẹ̀ níbí tí ẹ bá fẹ́ kí a fi àwọn abala ìwé-ìròyìn tó nbọ̀ ránṣẹ́ sí yin, ẹ tún fi orúkọ yín sílẹ̀ níbí tí ẹ bá fẹ́ kí á ké sí yín fún ìtumọ̀ àwọn abala ìwé ìròyìn wa ní ọjọ́ iwájú.

  • Àwọn Ìlànà Ìgbófìnró Àkọ́kọ́ - A ti ṣe àtẹ̀jáde Àwọn Ìlànà Ìgbófìnró Àkọ́kọ́ fún Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí lórí meta ní oríṣiríṣi èdè. Àwọn ìlànà yìí ní àwọn ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ titun, ó sì pèsè ìmọ̀ràn lórí àwọn ètò ìgbófìnró ìbílẹ̀. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Àtúnyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ inú Ìlànà Ìgbófìnró - Kí a tó parí àwọn ìlànà ìgbófìnró, àgbéyẹ̀wò àti ìjíròrò gbọdọ̀ wáyé pẹ̀lú àwọn ará Wikimedia. Àwọn olùṣètò ti ṣètò àwọn wákàtí àti ìpè ìjíròrò lákòkó àgbéyẹ̀wò yìí. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Àwọn Wákàtí àti Ìpè Ìjíròrò - Láti gbọ́ èrò àwọn ará àjọṣepọ̀ lórí àwọn ìlànà ìgbófìnró àkọ́kọ́ ti àwọn ìgbìmọ̀ fún kíkọ ti gbékalẹ̀, Àwọn olùṣètò UCoC yí ó ṣ'ètò wákàtí ìjíròrò ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Ìpalẹ̀mọ́ Wikimania - Àwọn olùṣètò ṣètò Ìjókò ìjíròrò ní Wikimania 2021, tí ó ní àwọn ará ìgbìmọ̀ onígbọ̀wọ́ àti òṣìṣẹ́ WMF. Ìjókò yìí pèsè àwọn ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ lórí bí a ṣe kọ Àwọn Ìlànà Ìgbófìnró Àkọ́kọ́ yìí, àti àwọn ìgbésẹ̀ tí à ngbèrò. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Ìtúmọ̀ - Bí ó ti jẹ́ wípé ọ̀pọ̀ lára àwọn ará Wikimedia ni kọ̀ gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì, síbẹ̀ UCoC tabá gbogbo ará, iṣẹ́-àkànṣe káàkiri Àjọṣepọ̀ Wikimedia, ó jẹ́ ohun pàtàkì láti pèsè àtìlẹ́yìn tó péye fún àwọn èdè lákòkò ètò yìí. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Búlọ́ọ̀gì Diff - Wo àwọn àtẹ̀jádè titun lórí ètò UCoC nínú Búlọ́ọ̀gì Diff ti Wikimedia. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Ètò Ìdìbò Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ WMF 2021 - Jọ̀wọ́ ka àgbékalẹ̀ àwọn olùdíje kí o sì dìbò!(ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)