Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí/Àwọ̀n ìjíròrò 2021/Ìkéde

From Meta, a Wikimedia project coordination wiki
Jump to navigation Jump to search
This page is a translated version of the page Universal Code of Conduct/2021 consultations/Announcement and the translation is 100% complete.
Other languages:
Bahasa Indonesia • ‎Bahasa Melayu • ‎Deutsch • ‎English • ‎Hausa • ‎Igbo • ‎Nederlands • ‎Yorùbá • ‎español • ‎français • ‎polski • ‎svenska • ‎čeština • ‎русский • ‎українська • ‎العربية • ‎فارسی • ‎ไทย • ‎中文 • ‎日本語

Ìpele Ìkejì Àlàkalẹ̀ Gbogboògbọ̀ fún Ìhùwàsí

Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí (UCoC) yìí ṣ'ètò ìpelẹ̀sẹ̀ iwà tí ó bójú mu fún àjọṣepọ̀ Wikimedia àti àwọn iṣẹ́ àkànṣe rẹ̀ẹ̀. kárí àgbáyé. Iṣẹ́ yìí wà ni ipele ìkejì lọ́wọ́, pẹ̀lú ìjíròrò lóri bí a ṣelè gbé òfin yìí ró. O lè kà si lóri iṣẹ́ yìí nípa lílọ sí ojú-ewé rẹẹ̀.

Ìgbìmọ̀ Abánikọ:Ìpè fún ìdarapọ̀

Wikimedia Foundation ngba àwọn olùfarajìn lọ́wọ́ láti darapọ̀ mọ́ ìgbìmọ̀ tí yíò kọ bí a ṣelè gbé òfin UCoC ró. Àwọn olùfarajìn lórí ìgbìmọ̀ yìí yó jọ̀wọ́ láàrin wákàtí méjì sí mẹ́fà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, láti oṣù kẹ́rin títí dé oṣù kéje, àti láti oṣù kẹ́wà sí oṣù kọ́kànlá. Ó ṣe pàtàkì fún ìgbìmọ̀ yìí láti ní onírúurú ènìyàn, tí ó ní oríṣiríṣi ìrírí, yálà àwọn oníṣé tí óti pẹ́ nínú àjọṣepọ̀ yìí tàbí àwọn tí ó ṣẹ̀ darapọ̀, àti àwọn tí ó ti jẹ́ olùfaragba ìyọnu lọ́nà kan tàbí òmíràn, pẹ̀lú àwọn tí ati fi èsùn èké ìyọlẹ́nu kàn.

Láti f'orúkọ sílẹ̀ tàbí mọ̀ si nípa ètò yìí, wo Àlàkalẹ̀ Gbogboògbọ̀ fún Ìhùwàsí/Ìgbìmọ̀ Abánikọ

Ìjíròrò 2021: Àkíyèsí àti ìpè fún àwọn olùfarajìn/onítúmọ̀

Láti 5 April - 5 May 2021, àwọn ìjíròrò yí ò wáyé nínu ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́ àkànṣẹ Wikimedia lórí ìgbófinró UCoC. À nwá àwọn olùfarajìn láti túnmọ̀ àwọn ohun èlò pàtàkì àti láti darí àwọn ìjíròrò ní èdè tàbí iṣẹ́ Wikimedia wọn nípa lílo àwọn ìbéèrè pàtàkì tí a dá lábàá. Tí ó bá wù ọ́ láti farajìn fún ọ̀kan lára àwọn ipọ̀ wọ̀nyí, jọ̀wọ́ késí wa nínú irú èdè tí ó bá rọrùn fún ọ.

Láti mọ̀ si nípa iṣẹ́ yìí àti àwọ̀n ìjíròrò míràn tí o nlọ lọ́wọ́, wo Àlàkalẹ̀ Gbogboògbọ̀ fún Ìhùwàsí/Àwọ̀n ìjíròrò 2021.

-- Xeno (WMF) (ọ̀rọ̀)