Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí/Àwọ̀n ìjíròrò 2021/Ìgbófìnró

From Meta, a Wikimedia project coordination wiki
Jump to navigation Jump to search
This page is a translated version of the page Universal Code of Conduct/2021 consultations/Enforcement and the translation is 100% complete.
Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí

Ojú ewé yìí ṣe àkójọ àwọn ìjíròrò àti ìkànsí ìbílẹ̀ fún Ipele kejì àkànṣe Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí (UCoC), tí ó wáyé láti oṣù kíní títí dé oṣù kéta, ọdún 2021. A jíròrò lóri bí a ṣele gbé òfin ìlànà UCoC ró pẹ̀lú àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia nípasẹ̀ oríṣiríṣi pẹpẹ tí ará kọ̀ọ̀kan má n lò sí. A lè ka àwọn èsì tí a rí lát'ọ̀dọ ìkànsí èdè kọ̀ọ̀kan ló ri:

 1. Èdè Árábìkì
 2. Èdè Afrikani
 3. Èdè Bengali + Èdè Ti Assam + Bishnupriya
 4. Wikimedia Commons
 5. Èdè Kòríà
 6. Èdè Yíbò + Èdè Hausa + Twi
 7. Èdè Indonéṣíà
 8. Èdè Ítálì
 9. Èdè Matihi + Èdè Newari + Bhojpuri + Doteli
 10. Èdè Malaya
 11. Èdè Nepali
 12. Èdè Póláǹdì
 13. Èdè Santali
 14. Wikidata
 15. Yorùbá

Ìfihàn

Ní Oṣù kẹ́wà ọdún 2020, lẹ́hìn ìparí ìgb'èsì sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ará àjọṣepọ̀, ìgbìmọ̀ fún kíkọ parí Ọ̀rọ̀ ìmúlò Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí (UCoC). Awá darí Ọ̀rọ̀ ìmúlò yìí sí ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ àwọn Onígbọ̀wọ́ Wikimedia Foundation fún àtúnyẹ̀wò. Àwọn ìgbìmọ̀ àkànṣe UCoC bẹ̀rẹ̀ ìgbáradì fún ipele kejì, tí ó gba ìkànsí àwọn ará àjọṣepọ̀ lẹ́ẹ̀kàn si láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí a lẹ̀ fi gbé òfin gbogboògbò yìí ró. Kíkọ àwọn ìlànà tí yóò ta bá àjọṣepọ̀ Wikimedia kárí ayé jẹ́ iṣẹ́ tí ó l'ágbára lọ́ọ́tọ̀. Wíwo àwọn ọ̀nà ìgbófìnró tún fi kùn bí iṣẹ́ náà ti l'ágbára sí.

È yí jẹ́ òdodo pàtàkì jùlọ fún ètò tí a bá fẹ́ kí ó ṣiṣẹ́ tààrà nínu àwọn àkójọpọ̀ oríṣiríṣi òfin lórí àwọn àkànṣe wa. Ní fífi ọ̀rọ̀ yìí sọ́ọ́kàn, ẹ̀ka Trust & Safety ṣe ìwádì láti mọ̀ dájú àwọn ọ̀nà ìgbófìnró l'óri oríṣirísi àwọn àkànṣe wa. Nítorí bí àjọṣepọ̀ Wikimedia ṣe rúnilójú lọ́pọ̀ àti bí àwọn iṣẹ́ àwọn oríṣiríṣi àkànṣe wa ṣe yàtọ̀ sí, ó l'ágbára láti ṣe àkọ́pọ̀ àti àyẹ̀wọ̀ bí ìjọba kan yíó ṣe ní ipa tó.

Ìgbìmọ̀ àkànṣe yìí gbàsílẹ̀ iye èsì tí wọ́n lè gbà láti le ṣ'àwòrán, l'óye, àti mọ̀'yàtọ̀ oríṣiríṣi àwọn ètò ìgbófìnró káàkiri àwọn ará àjọṣepọ̀ yìí. Lára rẹ̀ ni wíwo àwọn ará àti àkànṣe tí ó ní àwọn ìgbìmọ̀ ìjọba, bíi ArbCom, Checkuser àti Bureaucrat tí wọ́n wo àwọn èsùn ìwà wíwù. Àwọn ìgbìmọ̀ ná ṣe ìtúsí wẹ́wẹ́ àwọn àbùdà bí ìjáfáfá ojú-ewé ìkédè fún àwọn alákòso àwọn isẹ́ àkànṣe wọ̀nyìí, ìwàláàyè ètò kòtẹ́milọ́rùn, àti àwọn oníṣẹ́ tí a ti dádúró láàrín ìgbà kan. Mímú gbogbo eléyìí s'ọ́kàn, ìgbìmọ̀ yìí ya àwọn ará àjọṣepọ̀ yìí sí ẹgbẹ́ mètàa: àwọn ará tí ó ní ètò ìgbófìnró tó nípọn, àwọn ará tí ó ní ètò ìgbófìnró tí ó dójú ìwọ̀n, àti àwọn ará tí kòní ètò igbofinro tó ṣee gbọ́kànlé.

Ẹgbẹ́ náà gba àwọn olùṣètò mẹ́tàa sí'ṣẹ́ lát'òri ẹ̀ka kọ̀ọkan, nípa ríro ìrírí olùṣètò kọ̀ọkan l'órí àwọn iṣẹ́ àkànṣe wọn, ìmọ̀ ẹ̀dẹ̀ wọn, àti ìmọ̀ àwọn oríṣiríṣi ẹgbẹ́ nínú àjọṣepọ̀ yìí.

Ní Oṣù kíní ọdún 2021, ìgbìmọ̀ iṣẹ́ àkànṣe UCoC ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn ìjíròrò àti ìkànsí fún àwọn èdè ìbílẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn olùṣètò onírúurú èdè mẹ́sàn tí wọ́n báwa darí àwọn ìjíròrò fún àwọn ará àjọṣepọ̀ mọ́kànlélógún, tí ara wọn jẹ́ Wikidata ati Commons.

Òṣùwọ̀n ìkópa

Engagement from different communities.png

Ètò ìjíròrò àti ìkànsì yìí bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan l'óri gbogbo àwọn èdè tí a dojúkọ. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìkédè l'óri ojú-ewé ìkédè àti abẹ́-igi àwọn iṣẹ́ àkànṣe wọ̀nyìí. Lẹ́hìn èyí ni ìjíròrò bẹ́rẹ̀ nínu àwọn oríṣiríṣi pẹpẹ tí àwọn ará àjọṣepọ̀ náà lò sí.

L'ákòtán, ètò ìjíròrò àti ìkànsí ọlọ́sè-mẹ́fà yìí pín sí ipele mẹ́tàa. Ipele àkọ́kọ́ ni ìpè fún ìkópa l'órí ojú-ewé ìkédè àwọn iṣẹ́ àkànṣe àti orí social media àwọn ará àjọṣepọ̀. A ṣe eléyì láti jẹ́ kí àwọn ará mọ̀n nípa ìbẹ̀rẹ̀ ìjíròrò wọ̀nyìí àti láti pè wọ́n wá sí ìjíròrò gbangba yìí lórí àkórí ìgbófìnró UCoC. Ipele ìkejì jẹ́ fífi ìwé-ìwádìí jáde. A ṣe àkíyèsí nínú ìkànsí tó kọjá wípé àwọn ará tó pọ̀ ló fẹ́ràn dídáhùn sí iwé-iwádìí gẹ́gẹ́ bí pẹpẹ tí ó pèsè àbò fún èrò wọn jù lọ. Nípasè àwọn ìwé-ìwádìí wa, ọ̀pọ̀ àwọn oníṣẹ́ ni ó fi èrò wọn hàn pẹ̀lú àbò fún ìdánimọ̀ wọn. Nítorínà, a ṣí ọ̀nà ìgb'èsì sílẹ̀ yìí sílẹ̀ fún ipele ìkejì ìkànsí yìí. A pín àwọn ìwé-ìwádìí yìí lórí ojú-ewé àwọn iṣẹ́-àkànṣe yìí, nítorí kí a lèrí èsì tí ó gbòòrò. Ipele ìkétà ìjíròrò àti ìkànsí yìí wo èsì àwọn ọlọ́dọ̀ni. A ṣètò àpéjọ oríṣiríṣi pẹ̀lú àwọn ará àjọṣepọ̀ lóri ẹ̀rọ ayélujára, asì ké sí àwọn oníṣẹ́ fún ìkópa ojú-ko-jú. Eléyì pèsè àyè fún ìjíròrò àtẹnuwá gbangba àti ìbádámọ̀ràn lóri àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbé òfin UCoC ró ní àwọn iṣẹ́ àkànṣe àwọn oníṣẹ́ yìí.

Pẹpẹ fún Ìkópa

Gẹ́gẹ́ bíí àwọn ìjíròrò àti ìkànsí ti ipele àkọ́kọ́, a pinnu àwọn pẹpẹ àti ọ̀nà tí ìkópa fi wáyé nípasẹ̀ àwọn àìní, ààyò àti àṣà àwọn ará àjọṣepọ̀ àti olùkópa tí ó wà nlẹ̀. Ìgbìmọ̀ olùṣètò gbìyànjú láti lo àwọn oríṣiríṣi ọ̀nà àti pẹpẹ tí wọ́n lè lò, láti rí dájú wípé àyè wà fún oríṣirísi àwọn oníṣẹ́ láti kópa nínú ètò ìjíròrò yìí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rọ̀ wọ́n lọ́rùn tó.

Àwọn pẹpẹ tí a lò fún àwọn ìjíròrò l'ásìkò ètò ìkànsí yìí

Ìgbìmọ̀ olùsètò gba èsì sílẹ̀ lát'ọ̀dò àwọn ará àjọṣepọ̀ 3553. Ònkà yìí tọ́ka sí iye àwọn oníṣẹ́ tí ó f'èsì ránṣẹ́, sùgbọ́n kò ka iye àwọn èsì tí a rí gbàsílẹ̀ papọ̀; àwọn oníṣẹ́ míràn fi èsì sí'lẹ̀ ní ọ̀nà tàbí pẹpẹ tó ju'kan lọ, sùgbọ́n a ka gbogbo èsì náà l'ọ́kàn. Asìtún yọ àwọn èsì tí ó jọra ní oríṣiríṣi pẹpẹ kúrò. Bí àpẹẹrẹ, tí oníṣẹ́ kan bá f'èsì ní pẹpẹ méjì tàbí jùbẹ́ẹ̀lọ (abẹ́ igi, social media, ìpè ayélujára, àpéjọ ojú-ko-jú, etc.), a ka èsì wọn ní ọ̀kan. Ṣùgbọ́n, ẹléyìí kòṣeéṣe tó bẹ̀ fún àwọn èsì ìwé-ìwádìí, nítorí ọ̀pọ̀ lára àwọn èsì tí a gbà sí'lẹ̀ ní ọ̀nà yìí ni wọ́n dá àbò bo ìdánimọ̀ wọn. Nítorínà, ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ wípé àwọn oníṣẹ́ tó dáhùn ìwé-ìwádìí tún f' èsì ní pẹpẹ míràn. Àwọn olùkópa 2995 ni ó dáhùn ìwé-ìwádìí, àwọn 558 sì kópa lórí àwọn pẹpẹ tí ókù.

Ìjìnlẹ̀-òye Àwọn Ìjíròrò àti Ìkànsí

Àwọn ìjíròrò àti ìkànsí èdè ìbílẹ̀ ṣe àmújáde àwọ̀n oríṣiríṣi èrò lórí ọ̀nà tí a lè gbà gbé òfin UCoC ró, ètò àwọn ìgbìmọ̀ agbófìnró, àti ètò àtìléyìn fún àwọn olùfaragba ìyọlẹ́nu.

A lè ka àwọn èsì lát'orí ìkànsí èdè kọ̀ọ̀kan ní ìsàlẹ̀:

 1. Èdè Árábìkì
 2. Èdè Afrikani
 3. Èdè Bengali + Èdè Ti Assam + Bishnupriya
 4. Wikimedia Commons
 5. Èdè Kòríà
 6. Èdè Yíbò + Èdè Hausa + Twi
 7. Èdè Indonéṣíà
 8. Èdè Ítálì
 9. Èdè Matihi + Èdè Newari + Bhojpuri + Doteli
 10. Èdè Malaya
 11. Èdè Nepali
 12. Èdè Póláǹdì
 13. Èdè Santali
 14. Wikidata
 15. Yorùbá

Àwọn èsì

Breakdown of demographics by gender identities.png
Breakdown of demographics by rights.png

Gẹ́gẹ́ bí a ti lérò, ìgbìmọ̀ olùṣètò gba oríṣiríṣi èrò sí'lẹ̀ lórí àwọn ọ̀nà àti irú ìjọba tí a lè fi gbé òfin ìlànà UCoC ró. Ipele ìkejì ìkànsì yìí tí ó dálórí ìjíròrò lórí ìgbófìnró UCoC, jẹ́ ìdámọ̀ràn igbangba. Eléyìí túnmọ̀ sí wípé, àwọn ìtakùrọ̀sọ tó gbòòrò ni ówáyé láàrín àwọn ará àjọṣepọ̀ àti àwọn olùṣètò. Nítorí pé ètò yìí jẹ́ ìjíròrò, kò fẹ́rẹ̀ ṣéeṣe láti fi òṣùwọ̀n sí àwọn èrò tí àwọn ènìyàn fi lélẹ̀ lórí àwọn ọ̀nà ìgbófìnró àti ìgbìmọ̀ agbófìnró. Àwọn ará gbà wípé ó ye kí a ṣètò ètò ìgbófìnró tí ó dángájíá fún UCoC. Ṣùgbọ́n àwọn èrò lórí àwọn ọ̀nà tí a lè fi gbé òfin ìlànà náà ró yàtọ̀ sí arawọn púpọ̀. Àwọn ìmọ̀ràn kan fi ìdí múlẹ̀ dájú, nígbàtí àwọn òmíràn kò dájú. Kò sí ètò kan tí àwọn ará ti yàn lápàapọ̀, tàbí ìpohùnpọ̀ kankan. A kíyèsí wípé àwọn ará àjọṣepọ̀ l'érò wípé gbígbé òfin náà ró ní ọ̀nà kan pàtó fún àjọṣepọ̀ kárí ayé kò yẹ rárá. Tí a bá gbée ró báyì, ètò náà yí ò ní láti gba oríṣiríṣi àtúnyẹ̀wò kọjá, kó tó lè ṣée lò fún àwọn ará àjọṣepọ̀.

Àwọn èrò tí a gbàsí'lẹ̀ lórí ọ̀nà àti ètò ìgbófìnró ni:

1. Ṣí'ṣe ìdásílẹ̀ àwọn ìgbìmọ̀ ìbílẹ̀ láàrin àwọn iṣẹ́-àkànṣe

Ìdásílẹ̀ àwọn ìgbìmọ̀ ìbílẹ̀ tí yí ò ṣe ìwádìí àti ìdájọ́ fún àwọn ẹ̀sùn fún ìhùwàsí tó lòdì sí ìwà ọmọlúàbí, jẹ́ àbá kàn tí ó lókìkí jùlọ nínú àwọn èsì tí a rí gbà lát'ọ̀dọ àwọn oríṣiríṣi èdè tí a kànsí. Àwọn ará kàn fẹ́ ìgbìmọ̀ ìbílẹ̀ tí yí ò rí bí ìgbìmọ̀ ArbCom, nígbàtí àwọn ará míràn fẹ́ kí a yan ẹgbẹ́ láàrín àwọn alákòso tí yí ò ma ṣe ìwádìí àwọn ẹ̀sùn ìyọlẹ́nu wọ̀nyí. Àwọn ará mìrán tún ṣe àtìlẹ́yìn fún èrò ṣí'ṣe ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ titun fún UCoC, kí a má ba dákún iṣẹ́ àwọn alákòso tó wà nlẹ̀. Ṣùgbọ́n, àtẹnumọ́ wáyé nínú ìkànsí yìí wípé ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa àwọn àṣà iṣẹ́-àkànṣe, ṣe pàtàkì fún ẹnikẹ́ni tí yí ò bá má ṣe ìwádìí àti ìdájọ́ àwọn ẹ̀sùn ìyọlẹ́nu lórí iṣẹ́-àkànṣe náà.

Fún àbá yìí, àwọn ará tó'pọ̀ ló tún sọ wípé kí ìgbófìnró yìí lè ṣi'ṣẹ́ bí ó ti yẹ, Wikimedia Foundation gbọdọ̀ ṣe àtìlẹyìn fún àwọn ìgbìmọ̀ ìbílẹ̀ kí wọ́n bá le pèsè àwọn irinṣẹ́ àti ohun èlò tí yí ò jẹ́ kí wọ́n ṣe ìwádìí tí ó péye àti ìdájọ́ tí ó tọ́ nínú àwọn iṣẹ́-àkànṣe ìbílẹ̀ yìí.

Ní ọ̀rọ̀ ìgbófìnró yìí, mo fẹ́ kí àwọn iṣẹ́-àkànṣe tí ó ní ìgbìmọ̀ ArbCom kí wọ́n ní ìjọba ti ara wọn, kí àwọn ará ìta kankan má lè dá oníṣẹ́ dúró fún ìwà wọn lórí iṣẹ́-àkànṣe yìí, nípa lílo òfin UCoC. [...] Ní èrò mi, àwọn ará àjọṣepọ̀ gbọdọ̀ ní ìjọba ti ara wọn; ìdásí WMF gbọdọ̀ wáyé ní àwọn ìgbà tí ìwádì bá tí kọjá agbára ti ìgbìmọ̀ ìbílẹ̀; eléyì kò gbọdọ̀ yípadà, nítorí lọ́wọ́lọ́wọ́ WMF síì nṣe ìdásí nípasè ohun tí wọ́n pè ní àwọn ìgbésẹ̀ ọ́fíìsì.

— Ará àjọṣepọ̀ Pólándìì

Lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn alákòso má nṣe ìdájọ́ àwọn ẹ̀sùn ìyọlẹ́nu nítorí UCoC àti àwọn òfin ìbílẹ̀ d'ara dé'ra, àwọn alákòso yìí jẹ́ àwọn tí ó yẹ kí ó ṣe ìgbófìnró UCOC. Yí ó yàmíl'ẹ́nu tí wọ́n bá fi àwọn steward sí ipò ìgbófìnró yìí nítorí ìwọ̀n ẹ̀sùn tí wọn yí ó ma rí gbà lát'orí gbogbo àwọn iṣẹ́-àkànṣe Wikimedia lè kà wọ́n láyà. Mi ò sì tún rò wípé ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ titun yẹ kí ó wáyé nígbàtí ati ní oríṣiríṣi ìgbìmọ̀ nlẹ̀ tí ó nṣe ìwádìí àti ìdájọ́ irú àwọn ẹ̀sùn báyìí.

— Ará àjọṣepọ̀ Wikidata

2. Ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ agbófìnró kárí-ayé

Èrò àwọn ará pín sí agbede méjì lórí bóyá kí ìgbìmọ̀ agbófìnró yìí gàba lórí ìgbìmọ̀ ìbílẹ̀ tàbí kí ó wà lọ́tọ̀. Gẹ́gẹ́ bí èrò èsì àwọn ará kàn, ìgbìmọ̀ kárí-ayé ṣe pàtàkì fún ìdarí tí a bá fẹ́ kí ìlànà bíi UCoC kí ó ṣiṣẹ́ bí ó ti yẹ. Ṣùgbọ́n, àwọn ará tópọ̀ ló tún ṣọ kedere wípé, àwọn kò fẹ́ ìgbìmọ̀ ná kí ó wá láti ọ̀dọ̀ Wikimedia Foundation, tàbí kí Wikimedia Foundation yan àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn èsì tí a gbàsílẹ̀ fẹ́ràn ìgbìmọ̀ kárí-ayé lábẹ ìdarí àwọn ará àjọṣepọ̀, bíi ArbCom. Wọ́n tún sọ wípé a gbọdọ̀ ṣe ètò gidi lórí irú àwọn ènìyàn tí yí ò wà nínú àwọn ìgbìmọ̀ yìí, ọ̀nà tí a ó gbà yàn wọ́n, àti ìgbà tí wọn yí ó lò ní bẹ̀.

Mo fara mọ́n ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ Ombudsman láti gbe òfin Àlàkalẹ̀ fún Ìhùwàsí ró, àwọn sysops náà sì le ṣisẹ́ ìgbófìnró náà. Tí iyàn bá wáyé láàrín àwọn oníṣẹ́ nípa rírú òfin Àlàkalẹ̀ fún Ìhùwàsí, a gbọdọ̀ yanjú ọ̀rọ̀ náà ní ìlànà tó tọ́. Ìbéèrè mi lẹ́yìn èyí ni bíí a ó ṣe dá ẹgbẹ́ ombudsman yìí sílẹ̀ nígbàtí ìjíròrò náà bá ti bẹ̀rẹ̀.

— Ará àjọṣepọ̀ Indonésìà

Ní èrò mi, ó dára kí a yan àwọn ẹgbẹ́ ènìyàn lára àwọn ará àjọṣepọ̀ (dandan kọ́ ni kí wọ́n jẹ́ alákòso) tí wọn yí ò ní ìbáṣepọ̀ tààrà pẹ̀lú Wikimedia Foundation.

— Ará àjọṣepọ̀ Àrábíkì

3. Àkójọpọ̀ ìgbìmọ̀ agbófìnró ìbílẹ̀ àti kárí-ayé

Èrò míràn tí ótún gbajúmọ̀ ni dídásìlẹ̀ ìgbìmọ̀ ìbílẹ̀ tí ó ní ọ̀nà tí àwọn oníṣẹ́ lè gba lọ s'ọ́dọ̀ ìgbìmọ̀ kárí-ayé fún ìwádìí àti ìdájọ́ kò tẹ́ mi lọ́rùn. Àwọn ará tún ṣàlàyé wípé àwọ́n ẹ̀sùn kan wà tí ìgbìmọ̀ ìbílẹ̀ kò ní lè ṣe ohun t'ópọ̀ nípa irú ìyọlẹ́nu náà. Àwọn irú ẹ̀sùn báyìí ni:

 • Àwọn ẹ̀sùn tí ó kan alákòso tàbí ọmọ ìgbìmọ̀ agbófìnró.
 • Àwọn ẹ̀sùn tí ó jẹ́ wípé àbò olùfaragba ìyọlẹ́nu kò dájú tí wọ́n bá gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ ìbílẹ̀
 • Ọ̀rọ̀ ẹ̀sùn náà rúnilójú púpọ̀

Fún àwọn àsànyàn yìí, àwọn ìmọ̀ràn tí ó lágbára tún wáyé fún ètò kòtẹ́milọ́rùn, tí àwọn olùfisùn lè gbà lọ sí ìgbìmọ̀ kárí-ayé fún àtúnyẹ̀wò tí ìdájọ́ ìgbìmọ̀ ìbílẹ̀ kò bá tẹ́ wọn lọ́rùn.

Ìgbìmọ̀ kárí-ayé yìí lèè ṣiṣẹ́ bí ìgbìmọ̀ kòtẹ́milọ́rùn tí yí ò wà nígbàtí oníṣẹ́ bá ti lo gbogbo àwọn irinṣẹ́ ìbílẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò sí ìyànjú.

— Ará àjọṣepọ̀ Yorùbá

Ní gbogbo ipele, i.e. lát'orí àwọn ará àjọṣepọ̀ títí dé àwọn olórí WMF, ìgbìmọ̀ gbọdọ̀ wà láti ṣe ìwádìí àti ìdájọ́ ẹ̀sùn àwọn ìwà tó lòdì sí òfin UCoC. Ní ipele àwọn ará àti iṣẹ́-àkànṣe, a lè yan àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ yìí nípasẹ̀ ìdìbò. Ìgbìmọ̀ yìí kò gbọdọ̀ ní ọmọ-ẹgbẹ́ tóju ènìyàn mẹ́rin sí máàrún lọ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ náà sì gbọdọ̀ jẹ́ obìnrin. Àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ obìnrin ló sì gbọdọ̀ ṣe ìwádìí àwọn ẹ̀sùn ìyọlẹ́nu tó bá tabá àwọn oníṣẹ́'bìnrin. A gbọdọ̀ ṣe'tò ìlànà àti òfin fún ìdarapọ̀ mọ́n ìgbìmọ̀ yìí.

— Ará àjọṣepọ̀ Santali

4. Ìgbìmọ̀ Trust & Safety ti Wikimedia Foundation

Àwọn èsì míràn tún tọ́ka sí wípé, àwọn kò tako èrò jíjẹ́ kí T&S kó àwọn ipa kọ̀ọ̀kan nínú ètò ìgbófìnró yìí lákòtán. Wọ́n rò wípé ọ̀nà yìí bójúmu nìkan fún àwọn ìgbà tí kò bá sí ohun èlò ìbílẹ̀ láti ṣ'ètò ìgbófìnró nínú iṣẹ́ àkànṣe tí ìṣẹ̀lẹ̀ ti ṣẹlẹ̀.

A lè ṣ'ètò àkójọpọ̀ ìgbìmọ̀ kárí-ayé àti ẹ̀ka T&S

— Ará àjọṣepọ̀ Wikimedia Commons

Lópìn ohun gbogbo, olùfarajìn ni gbogbo wa, ó sì ní iye àsìkò tí a ní fún iṣẹ́ yìí. Ṣé mo ṣetán láti jòkó nínú ìgbìmọ̀ láti wádìí òfin? Mi ò rò bẹ́. Iṣẹ́ tí mo fẹ́ràn ni láti ṣe àfikún sí àwọn àròkọ [...]. A ti ngbìyànjú láti dá irú ìgbìmọ̀ báyì kalẹ̀ nínú Wikipedia èdè Afrikaans fún bíi ọdún díẹ̀ sẹ́yìn. [...] Àwọn ènìyàn kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀sí àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ òṣèlú, ṣùgbọ́n ìmọ̀, nínú àwọn ẹyẹ àti ẹja àti ìdídò àti afárá àti òpópónà. Kò sí ìkankan nínú wa tí ó nífẹ̀sí òṣèlú, ati lo àkókò tó pọ̀jù lórí rẹ̀ gan báyìí.

— Ará àjọṣepọ̀ èdè Afrikaans

5. Àwọn ètò àti ìlànà ìfisùn

Ìpohùnpọ̀ wáyé fún ètò ìfisùn tí ó dá àbò bò ìdánimọ̀ àwọn olùfisùn. Àwọn olùṣètò kíyèsi wípé nínú ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́-àkànṣe, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìyọlẹ́nu ni kò dé ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ kankan nítorí wípé kòsí ètò ìfisùn tí ó dá àbò tó dájú bo olùfisùn. Eléyì jẹ́ òdodo ní àwọn iṣẹ́-àkànṣe kékèèké ní pàtàkì jùlọ. Àwọn olùṣètò kíyèsi wípé ìyọlẹ́nu nwáyé nínú àwọn iṣẹ́-àkànṣe yìí ju iye àwọn ẹ̀sùn tí à nrí lọ. Èyì jẹ́ ìròyìn fún àwọn olùṣètò yìí tí wọ́n ti lo odún mẹ́wà nínú àjọṣepọ̀ yìí. Eléyì túnmọ̀ sí wípé, ìbẹ̀rù àti sọ̀rọ̀ sókè wà láàrín ọ̀pọ̀ àwọn ará àjọṣepọ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lú, àwọn oríṣiríṣi àbùdá ni ó jẹ́ kí ìfisùn le, tí ó sì rúnilójú.

Àwọn ará ṣe àpẹẹrẹ irú àwọn ipò yìí tí àwọn oníṣẹ́ kò le fi ẹ̀sùn sùn:

 • Ìfisùn gẹ́gẹ́ bí èwe.
 • Ìfisùn àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tabá òfin tóní gbèndeke ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Níbíyìí, ọ̀pọ̀ lára rẹ̀ ni àwọn ẹ̀sùn tí ó jẹ́ wípé oníyọnu àti olùfaragba ìyọlẹ́nu wá láti ìjọba tí óyàtọ̀.
 • Ìfisùn nípa ìbánilòpọ̀ akọ sí akọ tàbí abo sí abo. Ìfisùn irú àwọn ẹ̀sùn báyìí kò wọ́ pọ̀, nítorí ìbẹ̀rù wípé kí wàhálà náà má baa mú ìdójútini wá.
 • Ìṣòro ní fífi ẹ̀sùn sùn lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ti re kọjá lọ
 • Ìfisùn tó tabá àwọn ènìyàn mímọ̀ láàrin àjọṣepọ̀ tàbí àwọn oníṣẹ́ tí ó di ipò agbára mú nínú àjọṣepọ̀. Eléyìí tún má nṣẹlẹ̀ ní ìdàkejì náà. Àwọn oníṣẹ́ tí ó di ipò agbára mú ní ìṣòro ní fífi ẹ̀sùn sùn.
 • Àwọn oníṣẹ́ okùnrin ma nsábà lọ́ra láti fi ẹ̀sùn ìyọlẹ́nu ìbálòpọ̀ sùn.
 • Ìfisùn tó la èdè kọjá.

Ní èyí tó jọmọ́ ohun tí ó nṣẹlẹ̀ ní àwọn ojú-ewé ayélujára tó gbajúmọ̀, ojú-ewé ọ̀rọ̀ àwọn iṣẹ́-àkànṣe Wikimedia lè ní bọ́tìnì fún fífi ẹ̀sùn sùn. Títẹ bọ́tìnì yìí yí ò darí olùfisùn lọsí ojú-ewé tí wọn yí ò ti lè sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀.

— Ará àjọṣepọ̀ Ítálì

Ó yẹ kí pẹpẹ ìfisùn oríṣiríṣi wà, pẹ̀lú èyí tí yí ò dá àbò bo ìdánimọ̀ àwọn olùfisùn àti olùfaragba ìyọlẹ́nu. Ṣùgbọ́n, pẹpẹ àbò yẹ kí ó pín sí ìfisùn ìwà òdì.

— Ará àjọṣepọ̀ Kòríà

Àwọn Èròńgbà

Ọ̀pọ̀ àwọn oníṣẹ́ ni ó sọ wípé àwọn ti jẹ́ olùfaragba tàbí jẹ́ ẹlẹ́rìÍ sí ìyọlẹ́nu nítorí iṣẹ́ wọn nínú Wikimedia. Ṣùgbọ́n, wọn kò lè fi ẹ̀sùn náà sùn, àti wípé, ìgbà tí ìfisùn wáyé, kò sí ohun tó tẹ̀yìn rẹ̀ yọ nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò wáyé lórí àwọn iṣẹ́-àkànṣe wikimedia. Ọ̀pọ̀ àwọn oníṣẹ́ ni ó wípé UCoC yẹ kí ó ta bá irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí.

Ókéré jù, àwọn ará àjọṣepọ̀ kan ṣe àtakò sí òfin ẹlẹ́yà-mẹ̀yà UCoC. Àwọn ará yìí kọ̀jálẹ̀ wípé àwọn oníṣẹ́ ti ìbálòpọ̀ akọ-abo wọn yàtọ̀ àti àwọn ẹlẹ́yà kékeré wà láàrin wọn. Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ lára àwọn olùdáhùn sí ìwé-ìwádìí sọ wípé ìbálòpọ̀ akọ-abo wọn yàtọ̀. Gẹ́gẹ́ bíi ìmọ̀ràn olùṣètò, kíkéde èsì yìí yí ó fa ìyapa síi láàrin àwọn ará yìí.

Ìkópa lát'ọ̀dọ̀ àwọn obìnrin àti àwọn ẹlẹ́yà kékeré síbẹ̀ kéré. Àwọn ẹni tí ó kópa ṣe bẹ́ẹ̀ nípa àwọn pẹpẹ ìkọ̀kọ̀. Nínú àjọṣepọ̀ kan, àwọn obìnrin fi ara wọn hàn nínú ìwé-ìwádìí, ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀bẹ̀ wípé kí olùṣètò máà fi ìdánimọ̀ akọ àti abo wọn hàn ní gbangban. Eléyìí jẹ́ ìyàlẹ́nu fún olùṣètò, tí ó rò tẹ́lẹ̀ wípé kòsí obìnrin láàrin àjọṣepọ̀ rẹẹ̀, ṣùgbọ́n àbò wáà fún àwọn obìnrin. Ó jásí wípé àwọn obìnrin pọ̀. Ìmọ̀ yíì kò jẹ́ ohun tí ó gbajúmọ̀, nítorí àwọn obìnrin kò fẹ́ fi ara wọn hàn.

Àwọn èrò tó ṣe pàtàkì

Ókéré jù, àwọn ará àjọṣepọ̀ méjì ṣọ wípé àwọn kò fẹ́ ìdásí Wikimedia Foundation nínú ètò ìjọba ìbílẹ̀ àwọn. Láti dẹ́kun èyí, wọ́n ṣetán láti ṣe gbogbo ohun tí yí ò gbà láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ sí ètò ìjọba wọn. Lọ́wọ́lọ́wọ́, ọ̀kan lára àwọn àjọṣepọ̀ yìí ti n ṣiṣẹ́ lórí àwọn òfin ìbílẹ̀ wọn láti jẹ́kí ó jọmọ́ òfin UCoC, wọ́n sì ti nro àwọn ọ̀nà tí ìgbófìnró yí ò ti wáyé fún àwọn ẹ̀sùn tí ipá wọn ká.

Ní ìlòdì sí èyí, àwọn àjọṣepọ̀ kékeré ṣọ wípé àwọn fẹ́ràn láti lo àkókò àti ohun èlò wọn láti máa ṣe àtúnṣẹ́ sí àwọn àròkọ lórí iṣẹ́-àkànṣe wọn. Nítorínà, wọn yóò nílò àtìlẹ́yìn Wikimedia Foundation láti ṣètò àwọn òfin àti ìjọba tí yí ò báá UCoC mu. Ọ̀pọ̀ lára àwọn àjọṣepọ̀ tí kò kéré tàbí pọ̀jù, ní èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa kókó yìí. wọ́n fẹ́ràn ọ̀nà tí yí ò pèsè àtìlẹ́yìn láì dí àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tó wà nlẹ̀ lọ́wọ́.

Ìpè fún ẹgbẹ́ àtìlẹ́yìn

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ará àjọṣepọ̀ ni ó mú àbá wá fún ìdásìlẹ̀ ẹgbẹ àtìlẹ́yìn fún àwọn olùfaragba ìyọlẹ́nu. Gẹ́gẹ́ bí àwọn èsì tí a gbàsílẹ̀, lẹ́yìn ìfisùn, ẹgbẹ́ mẹ́ta ni olùfaragba má ndojú kọ - ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹ́ tí ó gbè ti oníyọnu, ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹ́ tí ó fẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà ní yànjú láì sí ojú ìsájú, ọ̀kan sì tún jẹ́ ẹgbẹ́ tí ò bá olùfaragbà kẹ́dùn. Fún olùfaragba ìyọlẹ́nu tó nla oríṣiríṣi ìpọ́njú kọjá lọ́wọ́, ó ṣe pàtàkì kí ẹgbẹ kẹ́ta wà ní gbogbo ìgbà. Ẹgbẹ́ àtìlẹ́yìn yí ò tún ki àwọn ènìyàn láyà láti sọ̀rọ̀ sókè fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kékeré, nítorínà yóò dẹ́kùn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nlá.

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ará àjọṣepọ̀ ló ṣàlàyé wípé irú ẹgbẹ́ báyì yẹ kí ó wà kárí-ayé. Àwọn ará àjọṣepọ̀ kọ̀ọ̀kan dábàá ṣíṣẹ̀dá pẹpẹ tàbí ìkànnì tí àwọn ènìyàn yí ò le wá láti gba àtìlẹ́yìn, nígbàtí àwọn ará àjọṣepọ̀ míràn sọ wípé ẹgbẹ́ ìkọ̀kọ̀ kékeré ni yí ò pèsè àbò jùlọ. Ìjíròrò yìí mú àwọn èrò wá, ṣùgbọ́n ìṣẹ̀dá irú ètò báyìí yí ò nílò iṣẹ́ gidi, ní pàtàkì jùlọ láti dẹ́kùn ìbàjẹ́ ẹgbẹ́ náà.

Ohun tí ó kù

A ó dà ìgbìmọ̀ kíkọ sílẹ̀ tí yí ò ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn èsì tí a gbàsílẹ̀ lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia. Ìgbìmọ̀ yìí yóò gbèrò ìmọ̀ràn lórí àwọn ètò ìgbófìnró tí ó yẹ, fún Ìgbìmọ̀ àwọn Onígbọ̀wọ́ Wikimedia Foundation.