Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí/Ìwé Ìròyìn/3

From Meta, a Wikimedia project coordination wiki
This page is a translated version of the page Universal Code of Conduct/Newsletter/3 and the translation is 96% complete.
Ìròyìn Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí
àtẹ̀jáde titẹ́lẹ̀ àtẹ̀jáde tókàn

A kí yin káàbọ̀ sí abala ìkẹ́tàa Ìròyìn Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí! Ìwé ìròyìn yìí yio ran àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tó nṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí ìlànà yìí, yí ó tún pín àwọn ìròyìn, ìwádìí, àti àwọn àpèjọ tó jọmọ́ UCoC tó nbọ̀ lọ́nà. A pè yín láti fún wa ní àwọn èsì tàbí àbá lórí àwọn abala ìwé-ìròyìn yìí tó nbọ̀ ní ojú-ewé ọ̀rọ̀ ìròyìn UCoC. E tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti ma túnmọ̀ àwọn abala ìwé-ìròyìn yìí sí èdè ìbílẹ̀ yín, àti pínpín ìwé-ìròyìn yìí ni àwọn ojú-ewé àti pẹpẹ ìjíròrò fún àwọn ará yín.

Jọ̀wọ́ rántí láti fi orúkọ sílẹ̀ níbí tí ẹ bá fẹ́ kí a fi àwọn abala ìwé-ìròyìn tó nbọ̀ ránṣẹ́ sí yin, ẹ tún fi orúkọ yín sílẹ̀ níbí tí ẹ bá fẹ́ kí á ké sí yín fún ìtumọ̀ àwọn abala ìwé ìròyìn wa ní ọjọ́ iwájú.

Adúpẹ́ fún kíkà àti ìdásí yin.

Àwọn Ìlànà Ìgbófìnró Àkọ́kọ́

A ti ṣe àtẹ̀jáde Àwọn Ìlànà Ìgbófìnró Àkọ́kọ́ fún Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí lórí meta ní oríṣiríṣi èdè. Adúpẹ́ lọ́wọ́ ìgbìmọ̀ fún kíkọ, tí ó pàdé fún ọ̀pọ̀ oṣù láti kọ ìlànà ìgbófinró àkọ́kọ́ yìí, nípa ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn èsì tí a ti gbàsílẹ̀ lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará Wikimedia lákòókò ìkànsí UCoC.

Àwọn ìlànà ìgbófìnró àkọ́kọ́ ní àwọn ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ titun, bíi Òṣìṣẹ́ Ìgbófìnró àti Ìgbìmọ̀ Ìgbófìnró, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ. Ó tún ṣ'àlàyé àwọn àfojúsìn fún iṣẹ́ onítẹ̀síwájú àti t'onídàhún. Àwọn ìlànà yìí pèsè àwọn ìmọ̀ràn lórí ohun-èlò ìfẹ̀sùnsùn àti ìwádìí, ìmọ̀ràn lórí àwọn ètò ìgbófìnró ìbílẹ̀ àti ìmọ̀ràn lórí ìdáhùn sí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, pẹ̀lú àwọn àkórí pàtàkì míràn.

Ó yẹ láti mẹ́nubà wípé àwọn ìlànà ìgbófìnró UCoC kò parí síbí, a ó sì máa gbé yẹ̀wò ní ìgbà-dé-ìgbà fún àtúnṣe lẹ́yìn èsì àwọn ará àjọṣepọ̀, pẹ̀lú ìbámu pẹ̀lú Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí.

Àgbéyẹ̀wò Àwọn Ìlànà Ìgbófìnró Àkọ́kọ́

Kí a tó parí àwọn ìlànà ìgbófìnró, àgbéyẹ̀wò àti ìjíròrò gbọdọ̀ wáyé pẹ̀lú àwọn ará Wikimedia. Àwọn olùṣètò ti ṣètò àwọn wákàtí àti ìpè ìjíròrò lákòkó àgbéyẹ̀wò tí a fi sí 17 August 2021 títí dé 17 October 2021. À npè fún àwọn èrò àti ìdásí lórí ojú-ewé ọ̀rọ̀ ti àgbéyẹ̀wò ìlànà ní èdè k'edè, ojú-ewé àwọn ìtúmọ̀, àwọn ìjíròrò ìbílẹ̀, àti àwọn wákàtí àti ìpè ìjíròrò.

E lè tún fi èrò, àfikún, àti ìpèníjà yín hàn nípa fífi ìwé-ayélujára ránṣe sí ucocproject(_AT_)wikimedia.org. A ó ṣe àkójọ àwọn èsì tí a bá gbàsílẹ̀ lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará, Ìgbìmọ̀ fún Kíkọ yí ò gbéwọn yẹ̀wò, wọn yí ò sì ṣe àtúnṣe sí ìlànà ní bí ó bá ṣe yẹ.

Àwọn Wákàtí àti Ìpè Ìjíròrò

Àkópọ̀ Ìpè Ìjíròrò ti July 17

Abala ìjókò ìjíròrò tó wáyé ní 17 July jẹ́ àṣeyọrí pẹ̀lú àwọn olùkópa 20. Àwọn ará Àjọṣepọ̀ ti èdè Gẹ̀ẹ́sì, Faransé àti Spánísì darapọ̀ mọ́ ìjíròrò kárí-ayé náà, nígbàtí àwọn ará ti Germany ṣ'ètò ìjíròrò ti wọn lọ́ọ́tọ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lú ìjíròrò UCoC, a tún sọ̀rọ̀ lórí Strategy Àjọṣepọ̀ àti ìdìbò ti Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́. Lára àkòrí ìjíròrò ni àwọn ohun tí òfin náà tabá, ìpèníjà nípa ìyọlẹ́nu tí kò ṣẹlẹ̀ lórí wiki, àti bíí ìfẹ̀sùnsùn ìkọ̀kọ̀ ṣe tako ìfojúsùn wa lórí ìyanjú àwọn ọ̀rọ̀ iyàn.

Àwọn Wákàtí àti Ìjókòó Ìjíròrò láàkókò EDGR

Láti gbọ́ èrò àwọn ará àjọṣepọ̀ lórí àwọn ìlànà ìgbófìnró àkọ́kọ́ ti àwọn ìgbìmọ̀ fún kíkọ ti gbékalẹ̀, Àwọn olùṣètò Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí yí ṣ'ètò wákàtí ìjíròrò ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ní August 24, 31 àti September 7 ní 03:00 UTC àti 14:00 UTC. Àwọn ará olùṣètò yí ò wà níbẹ̀ láti jíròrò àti láti dáhùn àwọn ìbéèrè lórí àgbéyẹ̀wò àwọn ìlànà ìgbófìnró àkọ́kọ́ àti láti gbà èsì sílẹ̀ lákòkò ìpè náà. Ìjókò ìjíròrò tókàn yí ò wáyé ní September 18, ní 03:00 UTC àti 15:00 UTC, láàrín àkókò àgbéyẹ̀wò àwọn ìlànà ìgbófìnró àkọ́kọ́. À ngbèrò láti ṣ'ètò ìpè yìí ní iye èdè tí a bá lè ṣ'àtìlẹ́yìn fún. A ó kéde ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí èyí láìpẹ́.

Ìpalẹ̀mọ́ Wikimania

Àwọn olùṣètò ṣètò Ìjókò Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí ní Wikimania 2021 ní 16 August 2021. Ìjókò náà ní àwọn ará lórí Ìgbìmọ̀ fún Kíkọ UCoC Sandra Rientjes, Taylor 49, Barkeep49, àti Nahid Sultan, pẹ̀lú Maggie Dennis tó jẹ́ Igbákejì ààrẹ Community Resilience and Sustainability. Ìpàdé náà wáyé fún ìṣẹ́jú 45, pẹ̀lú olùkópa tó fẹ́ẹ̀ tó 80.

Ìjókò yìí pèsè àwọn ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ lórí bí Ìgbìmọ̀ fún Kíkọ ṣe kọ Àwọn Ìlànà Ìgbófìnró Àkọ́kọ́ yìí, àti àwọn ìgbésẹ̀ tí à ngbèrò. Àwọn olùkópa bèèrè àwọn ìbéèrè lórí àwọn ohun-èlò ìfẹ̀sùnsùn àti àwọn ọ̀nà ìgbófìnró UCoC, pẹ̀lú bíí àkótán ètò náà ṣe paapọ̀ mọ́n Strategy Wikimedia 2030. Lẹ́yìn ìjókò náà, ọ̀pọ̀ àwọn ará Wikimedia tí àkòrí náà wúlò fún lọsí tábílì wa ní community village láti túnbọ̀ pín àwọn èrò àti ìmọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn olùṣètò.

A ṣe ìgbàsílẹ̀ ìjókò ìjíròrò yìí, o sì le tún wò lórí Youtube. Àwọn àkọọ́lẹ̀ rẹ̀ náà wà lórí [$Etherpad gbangba].

Ìtúmọ̀

Bí ó ti jẹ́ wípé ọ̀pọ̀ lára àwọn ará Wikimedia ni kọ̀ gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì, síbẹ̀ Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí tabá gbogbo ará, iṣẹ́-àkànṣe àti gbogbo ohun tó jọmọ́ Àjọṣepọ̀ Wikimedia, ó jẹ́ ohun pàtàkì láti pèsè àwọn òfin, ìlànà àti àwọn ìwé-ọ̀rọ̀ ní ọ̀pọ̀ èdè, àti ní ọ̀nà tí ó rọrùn fún gbogbo ènìyàn láti ní òye UCoC. Ètò ìtúmọ̀ yìí jẹ́ ohun ìpèníjà, nítorí pípèsè ìwé-ọ̀rọ̀ ìtúmọ̀ tí ó níga kò rọrùn.

What guarantees better quality in translation is having it done by someone who not only understands the language, but also understands the context. This is why the MSG facilitators are now handling translations to better serve all communities. This includes, but not limited to, Arabic, Deutsch, Bahasa Indonesia, Español, Français, Italiano, Polski, Russian, Yoruba, among others. Not only that, but also they coordinate with other wikimedians and volunteers to help with the translation, as far as possible. This cooperation didn’t only enhance the quality of translation, but also helped provide the translation on-time.

Búlọ́ọ̀gì Diff

Èyí ni àwọn àtẹ̀jádè titun lórí ètò Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí nínú Búlọ́ọ̀gì Diff ti Wikimedia, tí ó lè wù ọ́ láti kà. Jọ̀wọ́ yẹ̀ wọ́n wò:

Ètò Ìdìbò Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ Wikimedia Foundation 2021

Àwọn olùṣètò Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí fẹ́ rán gbogbo àwọn olùgbọ́ wa létí wípé ètò ìdìbò Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ Wikimedia Foundation nlọ lọ́wọ́, yí ó sì parí sí 31 August. Jọ̀wọ́ lo ìṣẹ́jú kàn láti: