Jump to content

Ìṣàfihàn àwọn olùdíje sípò Ìgbìmọ̀ àjọ Wikimedia Foundation ti /2021/2021-07-02/2021

From Meta, a Wikimedia project coordination wiki
This page is a translated version of the page Wikimedia Foundation elections/2021/2021-07-02/2021 Confirmed Candidates and the translation is 100% complete.

2021 Ìdìbò sípò Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe ni yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Kẹrin oṣù Kejọ ọdún 2021. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wù láti díje sípò náà ni ó ní ànfaní àti fi orúkọ wọn sílẹ̀. Olùdíje Ogún forúkọ sílẹ̀ níbi ìdìbò ti ọdún 2021

Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe olùfọkàn tán ti Wikimedia Foundation ni wọ́n yóò ma ṣe iṣẹ́ ojú tó'lé ojú tó'ko fún gbogbo iṣẹ́ àkànṣe Wikimedia jákè-jádò agbáyé. Ìgbìmọ̀ yí ni lọ́kàn láti kọ́mọ lùbọ́ kí iṣẹ́ wọn ó lè peregedé. Wọ́n ti fi àwọn Ohun àmúyẹ mẹ́rin pàtàkì tí wọ́n ń wá lára olùdíje kọ̀ọ̀kan tí wọ́n yóò dara pọ̀ mọ́ wọn.

Gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ Wikimedia pátá lórílẹ̀ agbáyé ni wọ́n ní ànfaní láti dìbò fún ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá lérò wípé ó peregedé láì sí àní-àní. Lẹ́yìn èyí ni ìgbìmọ̀ náà yóò wá yan àwọn mẹ́run tí ìbò wọn kún jùlọ. Ṣíṣe àṣàyàn yí yóò bẹ̀rẹ̀ ní inú oṣù Kẹsàn án, tí àwọn adìbò yàn náà yóò lo sáà ọdún mẹ́ta gbáko

Báwo ni mo ṣe lè dara pọ̀?

Mọ̀ siwájú nípa àwọn olùdíje

Àwọn olùdíje káàkiri agbáyé ti forúkọ wọn sílẹ̀ fún ìdìbò náà Ìmọ̀ ra nípa àwọn olùdíje yí fúnra wọn yóò fún ọ ní ànfaní láti mọ̀ bóyá wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí ìbò rẹ. Nínú ìpolongo tí ó ń l9 lọ́wọ́, ibẹ̀ ni àwọn òndìbò ti ń fi àwọn ìbéèrè Ọláọ́kan-ò-jọ̀kan ṣọ́wọ́ sí àwọn olùdíje, ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn Òndíje yóò dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n bá bi wọ́n , àwọn ìdáhùn yí ni àwọn Ìgbìmọ̀ Elétò Ìdìbò yóò ṣe akọsílẹ̀ ìbéèrè àti bí wọ́n ṣe dáhùn rẹ̀ lẹ́kún-rẹ́rẹ́. Àwọn Òndíje yóò ní ànfaní láti fi fọ́rán àwòrán ara wọn lórí bí wọ́n ṣe fara wọn sílẹ̀ láti díje.

Kópa nínú àwọn ìpolongo ìbò

Àwọn alákòóso tí wọ́n ń ṣagbátẹrù fún ìdìbò yí tí ṣe agbékalẹ̀ àwọn ètò kan kalẹ̀ ní àsìkò ìpolongo ìbò yí. Ẹ lè mọ̀ nípa àwọn ètò yí ní orí Board election paje on Meta

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ọláọ́kan-ò-jọ̀kan Wikimedia káàkiri agbáyé ní ànfaní láti gbé ètò kalẹ̀ ní àwùjọ wọn. Ètò èyíkéyí tí wọ́n bá fẹ́ gbé kalẹ̀ ó bọ̀wọ̀ fún àsìkò olùdíje nítorí wípé a kò fẹ́ gba àkókò tí wọ́n ní láti fi ṣe nkan miran. Ẹ ṣe àkọsílẹ̀ ètò tí ó bá wù yín síbí: Board election page on Meta kí àwọn ènìyàn ó lè ri ètò yín. Àwọn Olùrànwọ́ àti Elétò ìdìbò yóò ràn yín lọ́wọ́ bí ẹ bá nílò wọn.

Dìbò

Dídìbò fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe ti ọdún 2021 yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Kẹrin oṣù Kẹjọ tí yóò sì kásẹ̀ nílẹ̀ ní ọjọ́ Keje oṣù Kẹ́jọ ọdún 2021. Àwọn elétò ìdìbò ti yan ìlànà "Single transferable Vote" láàyò fún ìdìbò ti ọdún yí. Ẹ lè ka nípa ìlànà yí níbi: Voting requirment, ìgbésẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ìbéèrè nípa ìdìbò náà.

Single Transferable Vote

Ìlànà ìdìbò yí yóò jẹ́ kí àwọn òndìbò ó ṣe ìgbéléwọ̀n àwọn olùdíje ní tẹ̀lé-n-tẹ̀lé. Ó tún ma fún àwọn òndìbò ní ànfaní láti sọ èrò wọn lórí olùdíje tí wọ́n bá fẹ́. Ìlànà yí tún fi lélẹ̀ wípé bí òdndíje tí o yàn láàyò bá ti jáwé olúborí tí ó sì ti ní ìbò tí ó pọ̀ jùlọ ṣáájú kí o tó dìbò fun, wọn yóò yí ìbò rẹ sí ọ̀dọ̀ ẹnikejì tí o tún yàn láàyò nínú àwọn Òndíje tí kò tii ní ìbò púpọ̀. Àwọn elétò ìdìbò wá fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Amọ́, ẹ tún ma gbọ́ nípa ìlànà yí siwájú si ní inú oṣù Kẹjọ.

jọ̀wọ́, jẹ́ olùpolongo ìdìbò yan yí kí àwọn ènìyàn lè ṣe àṣàyàn ẹni tí yóò wù wọ́n láti dìbò fún kí ìṣeẹ́ àkànṣe Wikimedia ó lè te siwájú pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ tuntun.

Ó dìgbà,

Ìgbìmọ̀ elétò ìdìbò.