Movement Charter/Overview/yo

From Meta, a Wikimedia project coordination wiki
This page is a translated version of the page Movement Charter/Overview and the translation is 100% complete.


Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀ yí ò jẹ́ ìwé àṣe tí ó fi ipa àti ojúṣè oníkálukú àti oníṣẹ́ hàn lórí àjọṣepọ̀ Wikimedia, tí ara rẹ̀ yíò jẹ́ ṣíṣ'ètò Ìgbìmọ̀ ìṣàkóso àgbáyé fún ìdarí àjọṣepọ̀ yìí. Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀ jẹ́ Strategy kan gbòógì fún Wikimedia. À nretí ètò ìfọwọ́sí tó gbòòrò, kí á tó sọọ́ d'àṣà.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìmọ̀ràn lát'òri ètò strategy, Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀ yí ò:

  • Ṣe ìpilẹ̀ fún àwọn ìwà, òye àti ìlànà fún àwọn òpó àjọṣepọ̀ yìí, tí ara rẹ̀ jẹ́ àwọn ipa àti òjúṣe Ìgbìmọ̀ ìṣàkóso àgbáyé, àwọn ará àkórí àti ẹ̀ka Wikimedia, pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ ìpinnu tó wà nlẹ̀ àti ti titun,
  • Ṣe ìpìlẹ̀ gbèndéke àti ìlànà fún àwọn ìpinnu ṣíṣe àti àwọn ètò tí ó kan àpaapọ̀ àjọṣepọ̀, láti fi òfin dè wọ́n kí ìgbékèlé lè wà lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará Wikimeda, bí àpẹẹrẹ, fún:
    • Ṣíṣ'ètò àbò fún àyíká tí ó f'àyè gba àjùmọ̀ṣepọ̀,
    • Ìrí dájú owó pípa àti pínpín kárí àjọṣepọ̀ l'ágbàyé,
    • Pípèsè ìtọ́sọ́nà tó s'ọ̀kan lórí bíi a ṣelè pín àwọn ohun èlò, pẹ̀lú àwọn ìlànà ìjíyìn tó péye.
    • Ṣíṣ'ètò bí ó ti yẹ kí àwọn ará àjọṣepọ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀, àti bí óti yẹ kí a jínyìn fún ara wa.
    • Ṣíṣe ìfihàn àwọn ìrètí fún ìkópa àti ẹ̀tọ́ àwọn olùkópa.

Kilode ti a nilo Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀?

Àjọṣepọ̀ yìí gbòòrò lọ́pọ̀lọpọ̀, a nílò ètò ìpinnu ṣíṣe tí ó gba èrò gbogbo ènìyàn wolé láì fi ti ẹlẹ́yàmèyà ṣe. À n wò láti jẹ́ kí ìgbékèlé àti ètò láàrín àwọn olùkópa àjọṣepọ̀ yìí, kó nípọn síi. A fẹ́ pín ìlànà tó ṣ'ọ̀kan lórí bí a ṣelè ṣíṣẹ́ papọ̀, àti bí a ṣelè mú Ìtọ́sọ́nà Strategy ṣe.

Ìdí fún ìkópa rẹ̀ẹ?

À nṣ'ètò Ìwé-Àdéhùn kárí Àjọṣepọ̀ wa. A nílò ìkópa lát'ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn oníṣẹ́ wa kárí àgbáyé, ní pàtàkì jùlọ lát'ọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ tí a kò fojúsí dáradára tẹ́lẹ̀. A ní láti gbọ́ àwọn èrò tó yàtò síra láti ní òye àwọn ibi tí èrò wa ti jọra àti àwọn ibi tí a ti nílò ìjíròrò si.

  • Èrò kọ̀ọ̀kan ló ṣe ọ̀tọ̀, ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti ní òye ohun tí Wikimedia jẹ́ síbẹ̀ si
  • Ènìyàn kọ̀ọ̀kan ni ó ní èrò ọ̀tọ̀ fún ọjọ́ iwájú àjọṣepọ̀ wa.
  • A ní láti ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì lórí ọjọ́ iwájú àjọṣepọ̀ yìí - ohùn rẹ jẹ́ alábàpín nínú ṣíṣe àwọn ìpinnu tó ní ìmọ̀.

Bí o ṣe lè kópa?