Jump to content

Universal Code of Conduct/Newsletter/2/Global message/yo

From Meta, a Wikimedia project coordination wiki
This page is a translated version of the page Universal Code of Conduct/Newsletter/2/Global message and the translation is 95% complete.
Outdated translations are marked like this.

Ìròyìn Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí - Abala Ìkejì

Ìròyìn Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí
Abala ìkejì, Oṣù kéèje 2021Ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn


A kí yin káàbọ̀ sí abala ìkejì Ìròyìn Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí! Ìwé ìròyìn yìí yio ran àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tó nṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí ìlànà yìí, a ó sì tún pín àwọn ìròyìn, ìwádìí, àti àwọn àpèjọ tó jọmọ́ UCoC tó nbọ̀ lọ́nà.

Tí ẹ kò bá tí ṣ'eléyìí tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ rántí láti fi orúkọ sílẹ̀ níbí tí ẹ bá fẹ́ kí a fi àwọn abala ìwé-ìròyìn tó nbọ̀ ránṣẹ́ sí yin, ẹ tún fi orúkọ yín sílẹ̀ níbí tí ẹ bá fẹ́ kí á ké sí yín fún ìtumọ̀ àwọn abala ìwé ìròyìn wa ní ọjọ́ iwájú.

  • Àtúnyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ inú Ìlànà Ìgbófìnró - Àwọn ìpàdé ìpìlẹ̀ ìgbìmọ̀ fún kíkọ ti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìsopọ̀ àwọn àkórí pàtàkì lórí ìgbófìnró, àti ṣíṣe ìfihàn àwọn ìwádìí lórí àwọn ètò tó wà nlẹ̀ àti àwọn ààfò láàrín àjọṣepọ̀ Wikimedia wa. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Ìwádìí lórí Àwọn Ìfojúsìn fun Ìyọlẹ́nu - Láti ṣ'àtilẹ̀yìn fún ìgbìmọ̀ fún kíkọ, Wikimedia Foundation ṣ'ètò iṣẹ́ ìwádìí tí ó dá lórí àwọn ìrírí ìyọlẹ́nu lórí àwọn iṣẹ́-àkànṣe Wikimedia. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Ìkànsí àti Ìjíròrò fún Àwọn Alámùjútó - Láti Oṣù Kẹ́fà, Ìpàdé àwọn alámòjútó lát'òri àwọn oríṣiríṣi iṣẹ́-àkànṣe Wiki ti nwáyé, láti jíròrò lórí bí ó ti yẹ kí ọjọ́-iwájú UCoC rí ní ìrísí kárí-ayé. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Àwọn Ìpàdé fún ìjíròrò - Àwọn olùṣètò UCoC lẹ́ẹ̀kàn si, ṣètò ìpàdé fún ìjíròrò, ní àkókò yìí fún àwọn ará elédè Kòríà àti àwọn olùkópa míràn lát'orí àwọn iṣẹ́-àkànṣe ti ESEAP, láti jíròrò lórí ìgbófìnró UCoC. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ Ìsọdàṣà UCoC lát'ọ̀dọ̀ Àwọn Ará Àjọṣepọ̀ - Láti ìgbà ìfọwọ́sí Ìgbìmọ̀ àwọn Onígbọ̀wọ́ WMF ní oṣù kéjì 2021, àwọn ààyè tí àwọn ará àjọṣepò Wikimedia ti lo ìlànà UCoC ngbòrò si. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Ago-iṣẹ́ Titun fún Ìgbìmọ̀ Adelé Ìwádìí fún Trust & Safety - Ìrètí wà tẹ́lẹ̀ fún ìparí ìgbìmọ̀ CRC ní 1 July. Ṣùgbọ́n, bí ó ti wá jẹ́ wípé ètò UCoC yí ò ṣẹlẹ̀ títí dé Oṣù Kéjìlá, ago-iṣẹ́ fún ìgbìmọ̀ CRC ti yípadà. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Wikimania - Àwọn olùṣètò UCoC ngbèrò láti wà lórí ètò Wikimania 2021, nípasè ẹ̀kọ́ ìjíròrò. Wọ́n tún gbèrò láti ní àwọn asojú ní Community Village àpèjọ náà. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Búlọ́ọ̀gì Diff - Wo àwọn àtẹ̀jádè titun lórí ètò UCoC nínú Búlọ́ọ̀gì Diff ti Wikimedia. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)