Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀/Ìgbìmọ̀ Olùkọ/Àwọn Òfin

From Meta, a Wikimedia project coordination wiki
This page is a translated version of the page Movement Charter/Drafting Committee/Principles and the translation is 97% complete.
Outdated translations are marked like this.


Ojú-ewé yí dá lé òfin tí a gbé kalẹ̀ fún Ìgbìmọ̀ Olùkọ́ Ìwé òfin Àdéhùn Àjọṣepọ̀ (MCDC). Wọ́n ṣàpèjúwe ìgbìmọ̀ yí ati pàá pàá wọn, iṣẹ́ wọn ati ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú àjọ Wikimedia

Àwọn Òfin náà

Ìpín kínní

Àwọ̀n 'Ìgbìmọ̀ olùfilọ́ọ́lẹ̀ ' (MCDC) ni wọ́n jẹ́ àkójọ awọn ènìyàn kan tí wọ́n ṣe akọsílẹ̀ Ìwé òfin Àdéhùn Àjọṣepọ̀

  • Àwọn MCDC ni wọ́n ní àṣẹ láti ṣagbékalẹ̀ lórí ìdìbò/ìtọ́ka ẹni tàbí ìyànsípò.
  • Àkọsílẹ̀ Ìwé òfin Àdéhùn Àjọṣepọ̀ ni ó nííṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ìwádí ati ìjíròrò tó lókìmí pẹ̀lú àwọn aṣojú ajọ náà kárí ayé. Àwọn ìjíròrò yí ni wọ́n dá lé awọn iṣẹ́ àkànṣe lábẹ́lé, awọn ikọ̀ aṣojú Wikimedia, ajọ WMF àti awọn tí wọ́n bá ajọ WMF dòwòpọ̀ níta.
  • Àwọn MCDC ni wọn yóò ma léwájú níbi gbígbé ìwé òfin àdéhùn àjọṣepọ̀ kalẹ̀ fún àjọ WMF. Ṣáájú kí wọ́n tó sọ awọn ìwé àdéhùn yí dòfin, yóò ti jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún gbogbo ẹ̀ka ajọ WMF pátá.

Ìpín Kejì

Àwọn MCDC ni wọn yóò ma ṣamúlò awọn àwọn kókó tí eọ́n bá ti mẹ́nu bà nínú awọn ìjíròrò gbogbo nínú agbékalẹ̀ òfin wọn.

Nígbà tí ó bá ṣe pàtàkì kí wọ́n ṣe àyípadà òfin, àwọn MCDC yóò ṣàlàyé yékéyéké ìdí tí ó fi ṣe dandan láti lè jẹ́ kí gbogbo ènìyàn mọ̀ọ́.

Ìpín Kẹta=

Àwọn tí wọn yóò jẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùkọ́ Ìwé òfin Àdéhùn Àjọṣepọ̀ yí yóò jẹ́ mẹ́ẹ̀dógún sí méjìdínlógún tí wọn yóò jọ ṣiṣẹ́ pọ̀.

  • Bí a bá rí ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀ yí tó fẹ́ fipò sílẹ̀, wọn yóò yan ẹlòmíràn sípò yí nípa lílo ìlànà tí wọ́n fi yan gbogbo wọn síbẹ̀.
    • Ìdí tí olùyàn yóò ṣe yani tó fẹ́
    • Ìgbìmọ̀ tabí àjọ WMF ni yóò yan ọmọ oyè

Ìpín Kẹrin

Àwọn òṣìṣẹ́ àjọ WMF ati àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ láti ìta yóò ma ran àwọn MCDC lọ́wọ́.

Ìpín Karàn ún

Àwọn Ìgbìmọ̀ Olùkọ́ Ìwé òfin Àdéhùn Àjọṣepọ̀ ni wọ́n yóò ma ṣiṣẹ́ wọ́n láì sí lábẹ́ àṣẹ ẹnikẹ́ni.

  • Àwọn Ìgbìmọ̀ Olùkọ́ Ìwé òfin Àdéhùn Àjọṣepọ̀ (MCDC) ni wọn yóò ma pinu láàrín ara wọn nípa ìlànà tí wọn yóò gbà láti ṣiṣẹ́ wọn láṣe yanjú nípa ṣiṣe agbékalẹ̀ ètò àti ìgbésẹ̀ wọn.
  • Àwọn MCDC yóò sì ma jábọ̀ ohun gbogbo fún ajọ WMF ati awọn ènìyàn gbogbo láìfepobọyọ̀.

Ìpín Kẹfà

Àwọn MCDC ni wọn yóò ma pinu ọ̀nà tí wọn yóò ma gbà fẹnu kò lótí ohunkóhun. Èyí yóò dálé gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn bá bùkátà lọ́dọ wọn.

Ìlànà yí ní yóò wúlò fún ìpinu ilé ati tìta tí wọ́n bá fẹnu kò lé lórí.

Ìpín Keje

Awọn MCDC yóò ma bá àwùjọ ẹ̀ka awọn aláfikún sọ̀rọ̀ lóòrè-kóòrè fún ètò tó mọ́yán lórí.

Ìpín Kẹjọ

Àsìkò tí wọn yóò fi ṣiṣẹ́ yóò dá lórí iye agbékalẹ̀, ìjíròrò ati àtúnṣe tí wọ́n bá ṣe nígbà tí wọ́n bá ń sọ àbá dòfin.

Ìpín Kẹsàn án

Awọn MCDC ni wọn yóò ma siṣẹ́ ní gbogbo àsìkò tí a bá ń gbé ọ̀pá àṣẹ lé ìjọba alákòóso àjọ WMF míràn lọ́wọ́. Lẹ́yìn èyí, awọn MCDC yóò túká, tàbí kí wọ́n wà níbẹ̀ títí di inú oṣù Kejìlá ọdún 2024 láti lè jẹ́ kí iṣẹ́ wọn kẹ́sẹ-járí.